DAYỌ AMUSA GBE FỌTO AFẸSỌNA Ẹ SORI AYELUJARA, IYALẸNU LO JẸ FAWỌN TO RI I - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 1, 2019

DAYỌ AMUSA GBE FỌTO AFẸSỌNA Ẹ SORI AYELUJARA, IYALẸNU LO JẸ FAWỌN TO RI I

Gbajumọ oṣerebinrin taye n gba ti ẹ lasiko yi, Dayọ Amusa ti fi ọkọ afẹsọna ẹ han fawọn ololufẹ ẹ kaakiri agbaye, laipẹ yi ni obinrin naa gbe fọto naa sori ẹka ayelujara.

Kii ṣe pe Dayọ Amusa dee de gbe fọto naa sita, ṣugbọn lara idi to fi gbe fọto olofẹ rẹ sita ni bo ṣe n kii ku oriire, to si n ba a ṣajọyọ ayẹyẹ ọjọ ibi to ṣe e.

Wale Ade l'AWIKONKO gbọ pe orukọ ọkọ afẹsọna Dayọ Amusa n jẹ, ọkunrin to fi orileede United States ṣebugbe naa si jẹ gbajumọ nidi iṣẹ mọto tita, ko da ti wọn tun sọ pe ko si ipinlẹ ti ko ni ileeṣẹ si lorileede Naijiria.

Fawọn to ba n tẹle dayọ Amusa lori ẹka ayelujara ẹ daadaa, wọn yoo mọ pe laipẹ hyi ni ọkan lara awọn ololufẹ ẹ n beere lọwọ ẹ pe ṣe o le gbe oun jade lọọ ṣe faaji, ati pe ṣe o le gba koun fẹ ẹ sile gẹgẹ bi iyawọ, ṣugbọn ti ko da ẹni naa lohun.

Ohun to n ya awọn eeyan lẹnu ni pe, ko tii sẹni to ri ọrekunrin pẹlu gbajumọ oṣerebinrin yi ri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI