ILU LE LASIKO AARẸ BUHARI, EBI N PA MI O – GBAJUGBAJA SỌRỌSỌRỌ PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 19, 2019

ILU LE LASIKO AARẸ BUHARI, EBI N PA MI O – GBAJUGBAJA SỌRỌSỌRỌ PARIWO SITA

Ẹ ma fi ọlọpaa wa mi kaakiri - Ọmọba

Beeyan ba ri bi gbajumọ sọrọ ori redio ati tẹlifiṣan nni, Babatunde Okunade tawọn eeyan tun n pe ni Ọmọba ṣ e n sọrọ, to si sọ pe kijọba apapọ orileede Naijiria, labẹ Ọgagun Muhammadu Buhari tete wa nnkan ṣe si ọrọ ebi to n pawọn araalu, paapaa oun lasiko yi, nitori pe ọrọ ebi naa ti n kọja oju tawọn eeyan fi n wo o, eeyan yoo fẹẹ le maa ba a sunkun.

Ọmọba Okunade to tun jẹ ilumọn ọn ka adẹrinpoṣonu naa to filuu Abẹokuta ṣegbugbe lo sọrọ naa lori fọnran oni-ṣẹju mẹfa kan to gbe sori ayelujara laipẹ, pe ki wọn ba oun fi ranṣẹ si Aarẹ Buhari, ko le tete wa nnkan ṣe.

Ọkunrin sọrọsọrọ naa to ti gba oriṣiriṣi aami ẹyẹ fun ipinlẹ Ogun lẹka ere idaraya yi ni ọna kan ṣoṣo tijọba Buhari le gba yanju iṣoro airi ounjẹ jẹ tawọn araalu n koju ni lati gbe igbimọ ti yoo ri sọrọ ounjẹ dide, ati pe ẹni naa ko gbọdọ jẹ olowo, bi ko ṣe lara awọn ti ebi n pa, nitori pe ẹni naa gan an lo le mọ ibi ti bata ti n ta awọn eeyan lẹsẹ.

Ninu ọrọ rẹ ninu fọnran naa lo ti sọ pe “Mo ki gbogbo ẹyin ti ẹ n wo mi, Babatunde Ọmọba Okunade lorukọ mi, ẹ ma binu pe mo fẹẹ gba diẹ ninu asiko yin. Ẹ gbiyanju nitori Ọlọrun, ẹ ba mi fi fọnran yi ranṣẹ kaakiri, ko le awọn ibi ti mo fẹ ko de, iyẹn ọdọ Aarẹ Buhari.

“Ẹ pin in kaakiri ẹrọ ayelujara bii Twitter, Facebook, WhatsApp, Instagram atawọn min in ti ẹ ba mọ. Ko si ẹni to le sọn awọn nnkan fun yin yatọ si awa mẹkunu, awọn minisita, gomina ko sọ ọ.

“Aarẹ wa, mo fẹ ki ẹ mọ pe lati 2015 ti ẹ ti wa lori oye, ilu le gidi gan an ni, boya ẹ fẹẹ gbọ, tabi ẹ kọ, mo ni lati sọ okodoro ọrọ. Nnkan le, nnkan ko si rọrun fawọn araalu rara. Awa ti iya n jẹ la le mọ. Ebi n pa wa, ẹlomin in le sọ pe ebi ko pa oun, ṣugbọn emi Babatunde Okunade n fi asiko yi sọ fun un yi pe ebi n pa mi o.

“Wọn le sọ pe mi o niṣẹ, iṣẹ kan ṣaa ni mo n ṣe bọ tẹlẹ, bi mo si ṣe wa yi, mi o kii ṣe ọmọ kekere mọ, o si ti logun ọdun ti mo ti wa nidi iṣẹ yi, iṣẹ yi naa si ni mo n ṣe ti mo fi n bọ ara mi ati ẹbi mi tẹlẹ. Mi o ni ajọṣepọ pẹlu oloṣelu kankan tori pe opurọ ni gbogbo wọn, oloṣelu ko le sọ otitọ ọrọ fun un yi laye yi, ṣugbọn awa ti a le sọrọ naa re e, ẹ ko si le ri wa nidi oṣelu, nitori pe a ko ni le purọ fawọn eeyan, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan wa naa ko fẹ otitọ.

“Aarẹ wa, lati 2015 ti ẹ ti de ni ebi ti n pa awa ọmọ Naijiria gidigidi gan an ni o. Iya to tiraka ran ọmọ ẹ nileewe, tọmọ naa si pada jade ileewe, ti ko wa ri iṣẹ fi ṣe, bawo ni ọmọ na ko ṣe ni i jale, ti ko ni lọọ darapọ mọ ẹgbẹ buruku, tabi ko ṣe Yahoo lati le jẹ ki mama ẹ naa kuro ninu iṣẹ ati oṣi.

“Ki i ṣe ẹjọ gbogbo awọn ọmọ to n ṣe iṣẹ aṣẹwo rara, iya lo sun wọn debẹ ki i ṣe pe o dun mọ wọn ninu, awọn naa fẹẹ jẹun, wọn fẹẹ mu, wọn si fẹẹ wọ aṣọ, nitori pe iṣẹ ni ko si, bi ẹyin naa ba wo bi a ṣe pọ to, diẹ la fi din ni miliọnu lọna igba (190million).

“Igbimọ gbọdọ wa to maa ri si ọrọ ounjẹ, ki i ṣe awọn olowo lẹ maa yan nitori pe iya ko jẹ wọn, Olowo ko le sọ nnkan to n ṣe mi, emi ni mo mọ ibi ti bata ti n ta mi lẹsẹ. Ẹ jẹ ka pe awọn eeyan lori bi ounjẹ ṣe maa pọ rẹpẹtẹ niluu. Awọn ti wọn n lọ siluu Oyinbo sọ pe awọn naa n tiraka lati lowo, ṣugbọn iya ounjẹ ko jẹ awọn nitori pe ijọba pese ounjẹ fun wọn.

“Ebi lo le ọpọ awọn eeyan de ibi ti wọn ti n ji eeyan gbe beere owo, a ko sọ pe nnkan ti wọn n ṣe dara, ṣugbọn ti ebi ba kuro ninu iṣẹ, iṣẹ ti buṣe o. Awọn kan ti n ẹ sọ pe ki n ma ṣe fọnran yi, pe ijọba maa mu mi, wọn a si pa mi, ṣugbọn mo nigbagbọ pe ko sẹni to le pa ẹni ti Ọlọrun ko pa.

“Babatunde Okunade lorukọ mi, ẹ ma daamu lati wa mi kaakiri, mo wa larọwọto yin bi ẹ ba fẹẹ ri mi lati ṣalaye lẹkunrẹrẹ siwaju sii. Ebi n pa mi o.”

Ọpọ awọn ti wọn wo fonran yi lo ṣi n ṣe ni kaayefi pe bawo ni gbajumọ sọrọsọrọ ṣe maa n sọ iru nnkan to to bayii sijọba, ṣugbọn oun tawọn kan n sọ ni pe ebi to n pa ọkunrin naa lo sun un debẹ, ati pe nnkan ko fi bẹẹ dan mọnran fun un mọ lasiko yi, to si nilo iranlọwọ gidi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI