LẸYIN ỌDUN MARUN TI PATRICK KURO LẸWỌN LO TUN LỌỌ PADA JALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 6, 2019

LẸYIN ỌDUN MARUN TI PATRICK KURO LẸWỌN LO TUN LỌỌ PADA JALE

Pupọ ninu awọn to gbọ nipa gendekunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), Faso Henry Patrick pe o ti ṣẹwọn ri, to si tun pada lọọ jale ni wọn n fi epe ranṣẹ sii pe ko ni i bọ nibẹ, ati pe kani oun naa mọ pe aṣiri oun yoo pada tu ni, bo ya ki ba ti jawọ ninu ole jija.

Ohun ta a gbọ ni pe ni nnkan bi aago meji oru lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi ni Patrick, ọmọ bibi ilu ijọba ibilẹ Idiato North, nipinlẹ Imo lọọ fi kọkọrọ gbogboniṣe (Master Key) ṣilẹkun abawọle (Gate) ile Oloogbe kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Mike Ugh to wa lẹyin ileeṣẹ to n ri sọrọ iwe irinna, Immigration, Idiroko nijọba ibilẹ Ipokia, to si ko ọpọlọpọ ẹru nibẹ. 

Ori orule la gbọ pe Patrick gba wọnu palọ ile naa, to si ko awọn dukia bii LG DVD, speakers (super woofer) meji, LG DVD player, 6by4.5 size mattress atawọn irun agbeleri obinrin (ladies attachments).

Ọkada ni won so pe Patrick gbe lo fi ko awon eru naa, asiko to n pada sile ni wpon lowo awon Fijilante te e, to si fe maa paro fun won, sugbon nigba ti te e ninu daadaa lo pada jewo pe ki won se oun jeje.

Nigba to n tesiwaju nipa igbesi aye e, o jewo pe oun ti sewon ri, ati pe odun 2014 ni won foun sile logba ewon Ilaro, bee lo tun je ko ye won akekoo ile eko gbogboniṣe ti MAPOLY niluu Abẹokuta loun jẹ.

Ọgbẹni Yusuf Mọruf to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ fijilante to fiṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe lẹsẹkẹsẹ ti Patrick ji jẹwọ fawọn lawọn ti tare sawọn ọlọpaa Idiroko lati tẹsiwaju iwadii ti wọn.

Bẹẹ lo tun fi kun ọrọ rẹ pe o gbawọn oṣiṣẹ wọn ni wahala pupọ ki wọn too ri mu, nitori pe wahala to ba wọn fa pọ diẹ, ṣugbọn tọwọ pada tẹ ẹ.

Lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, gbogbo akitiyan lati ba Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọrọ lo ja si pabo dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI