NITORI IJỌBA GOMINA YAHAYA BELLO, NGIJ ṢABẸWO SI ATTAH TILUU IGHALA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 11, 2019

NITORI IJỌBA GOMINA YAHAYA BELLO, NGIJ ṢABẸWO SI ATTAH TILUU IGHALA

Attah tiluu Igala, Ọba Michael Idakwo Ameh Oboni II ti ṣapejuwe Gomina ipinlẹ Kogi, Alaaji Yahaya Adoza Bello gẹgẹ bi Gomina to bọwọ fun Aṣa ati iṣe ipinlẹ naa, paapaa iluu Igala.

Ọba Ameh lo sọrọ naa lọjọ Fraide ana lasiko to n gbawọn oniroyin to n ṣewadi kulẹkulẹ lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Guild of Investigative Journalists (NGIJ) lalejo ni Aafin to wa niluu Igala, nipasẹ iṣẹ iwadii ijọba Gomina naa lati bi ọdun meloo kan sẹyin, eyi ti wọn ṣe lọ.

Ọba Attah to tun jẹ Alaga igbimọ afọbajẹ nipinlẹ naa ṣapejuwe Gomina Bello gẹgẹ bi aṣiwaju rere to fara jin fun iṣẹ iluu, to si ni afojusun rere fun ipinlẹ naa, paapaa pẹlu bi ọjọ ori ẹ ṣe kere laarin awọn Gomina yooku. 
O tun jẹ ko di mimọ pe Gomina Yahaya Bello lo nu omije kikoro kuro loju awọn nipinlẹ naa, tawọn si tun gbadura fun ijọba ẹ pe ko maa tẹsiwaju.

Ṣaaju asiko yi, Kọmureedi Wale Abydeen to lewaju awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọ pe awọn awuyewuye tawọn n gbọ lo mu kawọn gbera lati wa a tan imọlẹ sawọn nnkan to n ṣẹlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI