ONI LAYẸYẸ ỌJỌ IBI ṢẸGUN ỌKẸOWO, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ ATI ONIROYIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 25, 2019

ONI LAYẸYẸ ỌJỌ IBI ṢẸGUN ỌKẸOWO, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ ATI ONIROYIN

Ko too to ana lawọn eeyan ti n foju sọnọ fun ọjọ onii lati ki ọkan lara awọn gbajumọ sọrọsọrọ ati oniroyin to ṣẹṣẹ n dide bọ nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Oluwaṣẹgun Pẹlumi Ọkẹowo.
Yatọ si pe Ṣẹgun Ọkẹowo jẹ pedepede ati oniroyin, bẹẹ lo tun fẹran lati maa lu ilu, tẹ gita (Guilter), gba bọọlu, eyi gan lo jẹ ko yan ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona laayo.
Onii tii ṣe ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu karun ni Ọlọrun tun fi ọdun kan kun ọdun ọdọmọkunrin to n kọ iṣẹ pedepede lọdọ Ọmọba Babatunde Okunade.
Ọkan lara awọn oniroyin fun ileeṣẹ wa, AWIKONKO MEDIA CHANNEL ni Ṣẹgun Ọkẹowo, eyi la fi n fi ẹmi imoore han sii lonii to jẹ ayajọ ọjọ ibi ẹ.
Ẹ ba wa fi adura ranṣẹ sii.

Oriki Ṣẹgun Ọkẹowo

Oriki akọkọ
Itoku Ereke ja
Ọmọ A-file pogun
Ọmọ Alugbede gbede b’ọtja
Ogun o ni ja ja ko ja ile Itoku
Ọmọ afiju ilẹ Ijbu
Ọmọ to n foko r j Apena
Ọmọ gba Onigbedu Ajina
Ọmọ gba Onigbedu Aji lwl


Oriki Keji
Ọmọ ara Ake m’ajo meji
Ọmọ ajogbru ma jo gb’ẹk
Ọmọ ẹru ni n sin nni, ẹkọ kii si niyan
Ọmọ abilake igangan
Ọmọ eluku awo lolo
Ọmọ ologbedu bariba
Iyi wn n fawo ṣẹri toun akete ati ẹrin
Ọmọ bo le p’ẹja, ko p’ẹja
Ọmọ bo le pargidigba ko pargidigba
Mo pa igangan olodo afara dudu wowo
Ọmọ abilake ko nj igangan
Ọmọ oloke mrindinlogun
Ọmọ eleere mfa
Ọmọ ṣubu lade
Ọmọ agbade l’ọba lori
Ọmọ aroṣẹ f’Ọba j
Ọmọ lakeesi
Ọmọ ọsan la n binu
Ọmọ oru la a eka
Ika ti a ba e l’ọsan ko gbeni
Lakeesi Ọmọ a'oria lofin
Ki a ma gbohun agogo
Ọmọ Ọba laganran
Ọmọ ọlọti ido, Ọmọ ajirtutu
ba ni wn n j nile Alake majo
Ọmọ jun tan, o fawo
Ọmọ ta tan o f’ọja
Ọmọ kja o bẹ’gi dina
Ogbe o m’ẹni o ko o

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI