ỌTI ẸLẸRINDODO BIGI APPLE DI IBẸRU FAWỌN ARAALU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 10, 2019

ỌTI ẸLẸRINDODO BIGI APPLE DI IBẸRU FAWỌN ARAALU

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ Rite Foods Limited to n ṣe ọti ẹlẹrindodo to gbajumọ, tawọn eeyan n ra mu lasiko yi ti jẹ ko di mimọ lori ikanni ayelujara ti twitter wọn laipẹ yi pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ boya loootọ ni ohun tawọn eeyan n sọ nita lasiko yi pe ọti naa ti di ibẹru fawọn araalu, sibẹ ọkan awọn to n ra a mu ko balẹ rara.

Fawọn to ba mọ bo ṣe n lọ lasiko yi, wọn yoo ṣakiyesi pe ọti ẹlẹrindodo Bigi, paapaa eyi ti wọn pe ni Bigi Apple ti pe meji nita bayii, to mu kawọn eeyan maa beere lọwọ ara wọn pe 'e wo ni ogidi, e wo ni ayederu', ti ko si ṣeni to le sọ bo ṣe jẹ.

Kaakiri ori ayelujara lawọn ọmọ Naijiria, paapaa lawọn agbegbe ti wọn ti n ra ọti ẹlẹrindodo naa mu nilẹ adulawọ ni wọn ti n beere lati mọ boya ipele meji ni ọti Bigi Apple naa wa.

Ki i ṣe ahesọ tabi irọ pe ogunlọgọ ọti ati ọti ẹlẹrindodo ni wọn n ṣe aburọ wọn kaakiri orileede Naijiria, to si jẹ pe aimọye igba ni akara awọn to nidi iṣẹ naa ti tu sepo.

Awọn oniṣẹ iṣegun oyinbo ti fidi ẹ mulẹ lọpọ igba pe ki wọn ṣọra fun pupọ ninu awọn ọti ẹlẹrindodo ti wọn n mu lasiko yi, nitori pe wọn ṣakoba fun ara, ko si sidi meji bi ko ṣe pe awọn ayederu to pọ ninu awọn ọti naa lo n 'sakoba.

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i ṣeni ti wọn ti ṣakọsilẹ ẹ pe o kagbako iku ojiji, tabi pe o ko aisan lati ara ọti Bigi Apple titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ṣugbọn ohun tawọn eeyan n sọ ni pe o yẹ ki ileeṣẹ Rite Foods Limited ti tete gbe igbesẹ, ko too di pe nnkan pada yiwọ mọ wọn lọwọ.

Iwadii ti AWIKONKO ṣe laipẹ yi fi ye wa pe latigba ti Bigi Cola ti jade, lọpọ awọm eeyan ti pa awọn ọti ẹlẹrindodo to wa nita tẹlẹ bii Coke, Pepsi atawọn min in ti sẹgbẹ kan nitori pe ike wọn tobi.

Bawọn eeyan ṣe tẹwọ gba Bigi Cola yi lo mu ki ileeṣẹ naa gbiyanju lati gbe awọn min in bi i Bigi Apple, Bigi Tropical, Bigi Lẹmọn, Bigi Orange jade, tawọn eeyan si tun tẹwọ gba a.

Lara awọn alagbata ti wọn  b'AWIKONKO sọrọ laipẹ yi ta a forukọ bo laṣiri jẹ ko ye wa pe awọn mọto ti wọn ko awọn ọja naa wa fawọn naa lo n ko mejeeji wa, tawọn naa ko si ṣo pe ileeṣẹ Rite Foods Limited lo n ṣe wọn.

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan ni iwadii ṣi n lọ lọwọ, ti ileeṣẹ naa si sọ gẹgẹ bi atẹjade ti wọn gbe sori twitter pe awọn naa ṣi n ṣe iwadii.

Ohun tawọn eeyan n bẹbẹ fun bayii ni pe bi ileeṣẹ naa ba mọ pe awọn ko le dahun ibeere awọn araalu lori ayederu ati ojulowo Bigi Apple, ki wọn ti ileeṣẹ wọn pa ko too bẹrẹ si i ṣakoba fawọn to n muu. Ati pe o yẹ ki wọn ti gbe eyi to jẹ ojulowo sita, kawọn eeyan le mọ eyi ti wọn yoo ma a ra, dipo ki wọn maa ra mejeeji mu.

Sibẹ, gbogbo akitiyan lati ba awọn alakoso ileeṣẹ naa sọrọ lo ṣi n ka si pabo dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI