Ẹ TUN WO AWỌN ỌMỌ YAHOO TI WỌN FOJU BA ILE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 1, 2019

Ẹ TUN WO AWỌN ỌMỌ YAHOO TI WỌN FOJU BA ILE ẸJỌ

Ọjọ Tọside ijẹta yi ni ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn EFCC tun foju awọn ọdọmọkunrin mẹrin ati ọdọmọbinrin kan bale ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Benin, nipinlẹ Ẹdo.

AWIKONKO gbọ pe ẹsun marun un ọtọọtọ ni ajọ EFCC fi kan awọn marun un, eyi ti wọn ni wọn n lu jibiti ori ayelujara, ti a mọ si Yahoo-Yahoo, to si tako ofin jibiti ayelujara (Cybercrime) tọdun 2015.

Gabriel Akhibge, Isaac Christiana Nkemdirum ati Innocent Uyioshoria ni wọn kawọ pọyin niwaju Onidajọ A. A. Demi-Ajayi, ti wọn si lawọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn, amọ ṣa, wọn bẹbẹ fun idariji.
 
Awọn meji yooku ni Ọsawaru Samson ati Onineh Dickson Imaboyor tawọn naa kawọ pọyin niwaju Onidajọ M. G. Umar, Nigba ti Imaboyor sọ pe loootọ loun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣe ni Ọsawaru sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.

Latari eyi, ile ẹjọ ti sun igbẹjọ min in si ọjọ kẹtala, ọjọ kẹtadinlogun ati ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI