Ẹ WOJU AWỌN ỌDARAN TO N BẸ ỌPA EPO RỌBII KAAKIRI NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, June 26, 2019

Ẹ WOJU AWỌN ỌDARAN TO N BẸ ỌPA EPO RỌBII KAAKIRI NAIJIRIA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Boroboro lawọn gendekunrin marun kan ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji lo ju ki wọn maa bẹ ọpa epo n ka nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ wọn lọjọ Sande ọsẹ to kọja yi lagbegbe Magboro.

Awọn ọdaran marun tọwọ tẹ naa ni Akinwale Tajudeen, Isiah Ọlalekan, Friday Terry, Mayọkun Raheem ati Godwin Igho.

AWIKONKO gbọ pe ni nnkan bi aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa la gbọ pe awọn ọlọpaa ri wọn nibi ti wọn ti n ko awọn pẹtiroolu ti wọn ji wa sinu mọto.

A gbọ pe bi wọn ṣe kofiri pe awon ọlọpaa ti n kọja lagbegbe naa ni wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ, ṣugbọn tawọn ọlọpaa naa gba tọ wọn lẹyin, ti wọn si pada ri gbogbo wọn lahamọ ti wọn sapamọ sii.

Kẹẹgi lita aadọta mejila la gbọ pe wọn ti ji bu sinu mọto wọn ti nọmba idanimọ ẹ jẹ Lagos KSF 710 BM, tawọn ọlọpaa si wa gbogbo ẹ lọ si teṣan wọn to wa niluu Ibafo.

Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Baṣhir Makama ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa SARS ko wọn lọọ ṣe faaji diẹ lọdọ wọn, ki wọn too foju wọn bale ẹjọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI