GBOGBO ILEEṢẸ ELETO AABO FẸẸ ṢEPADE NLA L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 25, 2019

GBOGBO ILEEṢẸ ELETO AABO FẸẸ ṢEPADE NLA L'EKITI

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbogbo ile iṣẹ eleto aabo patapata lorilẹ-ede Naijiri ni wọn ti gbaradi lati forikori lọjọ Tọside ati Fraide ọsẹ yi nipa ibi ti wọn yoo gbe eto aabo ilẹ Yoruba gba, lati le dẹkun wahala ọjọ iwaju.

Awọn ile-iṣẹ eleto aabo bii Ologun, Ọlọpaa, Ọtẹlẹmuyẹ, Sifu Difẹnsi, NDLEA ati NAPTIP atawọn min in kaakiri orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti sọ pe awọn ṣetan lati ṣepade alaafia.

Ijọba ipinlẹ Ekiti labẹ Gomina Kayọde Fayẹmi lo fẹẹ ṣagbatẹru ipade eto aabo naa to nii ṣe pẹluu eto aabo ipinlẹ ati apapọ orilẹ-ede yi niluu Ado-Ekiti.

A gbọ pe gbogbo eto lo ti to lati jẹ ki ipade naa lọ nirọwọ irọsẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI