ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ ONDO LE AWỌN ALAGA IJỌBA IBILẸ ATAWỌN KANSẸLỌ DANU LỌSAN GANGAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 13, 2019

ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ ONDO LE AWỌN ALAGA IJỌBA IBILẸ ATAWỌN KANSẸLỌ DANU LỌSAN GANGAN

"Nibo la fẹẹ lọ, ibo ni ka ti bẹrẹ" lọrọ ibanujẹ to n tẹnu awọn alaga ijọba ibilẹ mejidinlogun atawọn kansẹlọ  mẹtalenigba (203) ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo le danu pe awọn ko nilo wọn mọ, nitori pe iṣẹ wọn ko wulo mọ.

Awọn alaga atawọn kansẹlọ naa la gbọ pe fidihẹ lasan ni wọn fi wọn ṣe latari pe ki awọn aaye naa ba a ṣofo lasan.

Oni ni aṣẹ naa waye, ti wọn si tun paṣẹ pe lile wọn danu ti wọn le wọn danu bẹrẹ lati onii bakan naa. ti wọn si ni gbogbo ẹru ijọba to ba wa lọwọ wọn ni ki wọn lọọ ko silẹ fun adari ẹka ile iṣẹ ijọba to n ri sọrọ ijọba ibilẹ nipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI