IWADII BẸRẸ LORI AWỌN ỌBA MARUNDINLỌGỌRIN TI WỌN YỌ N'IPO L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, June 8, 2019

IWADII BẸRẸ LORI AWỌN ỌBA MARUNDINLỌGỌRIN TI WỌN YỌ N'IPO L'OGUN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ijọba ipinlẹ Ogun labẹ akoso Gomina Dapọ Abiọdun ti gbe igbimọ ẹlẹni mẹfa kan dide lati ri si ọrọ awọn ọba marundinlọgọrin ti gomina ana, Sẹnetọ Ibikunle Amosun yan ko too gbe ijọba silẹ.

Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle la gbọ pe wọn yan gẹgẹ bi alaga igbimọ naa. Lara awọn to tun wa ninu igbimọ naa ni: Dagburewe tiluu Idọwa, Ọba Yinusa Adekọla; Ẹlẹpẹ tiluu Ẹpẹ, Ọba Adewale Ọṣibẹru; Aro tiluu Ẹgba, Oloye Yinka Kufilẹ akọwe agba tẹlẹri lẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, Ọgbẹni Babatude Oyẹti.

Igbimọ naa la gbọ pe gbogbo awọn Baalẹ ti wọn sọ di ọba atawọn Ọba tuntun ti gomina Amosun yan laarin oṣu keji ọdun yi si asiko to fi gbe ijọba silẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Gomina Dapọ Abiọdun fi sita lọjọ Fraide ana lo ti jẹ ko di mimọ pe lati ma jẹ ki wahala bẹ silẹ nipinlẹ Ogun lo mu ki wọn gbe igbesẹ naa to si tun jẹ ko di mimọ pe akọwe agba ẹka to n ri sọrọ oye jijẹ atijọba ibilẹ nipinlẹ naa, Ọgbẹni Lanre Ọṣọta ni yoo jẹ akọwe igbimọ naa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI