JUNE 12: ALAINITIJU NI ỌBASANJỌ, IWA ILARA LO N YỌ Ọ L'ẸNU - FAYỌṢE SỌKO ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉThursday, June 13, 2019

JUNE 12: ALAINITIJU NI ỌBASANJỌ, IWA ILARA LO N YỌ Ọ L'ẸNU - FAYỌṢE SỌKO ỌRỌ

Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ayọdele Peter Fayọṣe ti sọ pe alainitiju ni Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede yi, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ latari awọn ọrọ kungba-kungbe to n sọ si Aarẹ Muhammadu Buhari lori bo ṣe bọwọ fun Oloogbe Mọshood Kọlawọle Abiọla, ẹni tọpọ awọn eeyan gbagbọ pe oun lo jawe olubori idibo June 12, 1993.

Ori ikanni ayelujara ti twitter ni Ayọdele Fayọṣe ti sọkọ ọrọ naa, nigba to n tako ọrọ Oloye Ọbasanjọ to sọ pe ko yẹ ki Aarẹ Buhari ṣe awọn nnkan to ṣe lati mọ riri June 12, 1993.

Fayọṣe sọ pe ọkan pataki lara awọn to jẹ anfaani June 12 ni Ọbasanjọ, to si kuna lati ṣe awọn nnkan to yẹ ko ṣe lori June 12, pẹluu bo ṣe jẹ Yoruba bii ti Oloogbe MKO Abiọla nigba to fi wa nipo gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria.

O tun tẹsiwaju pe iwa ilara lo n yọ Aarẹ tẹlẹri naa lẹnu, to si loun gbe oṣuba kare fun Aarẹ Muhammadu Buhari fun bo ṣe bu ọla ati iyi fun Oloogbe MKO Abiọla gẹgẹ ẹni to jawe olubori ninu idibo ọdun 1993. 

Bẹ o ba gbagbe, ọdun to kọja ni Aarẹ Buhari ti sọ pe Naijiria yoo maa ṣayẹyẹ June 12 gẹgẹ ayajọ ọjọ eto oṣelu awaarawa, to si tun sọ Papa iṣere apapọ orilẹ-ede Naijiria to wa niluu Abuja lorukọ MKO Abiọla.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI