LẸYIN OṢU MẸFA TI WỌN ṢE IGBEYAWO, FATIMA GUN ỌKỌ RẸ NI ỌBẸ MAKANJẸ - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Sunday, June 23, 2019

LẸYIN OṢU MẸFA TI WỌN ṢE IGBEYAWO, FATIMA GUN ỌKỌ RẸ NI ỌBẸ MAKANJẸ

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi ni ko tii sẹni to le sọ ibi ti ọrọ iyaale ile kan, Fatima yoo ja si, latari bi wọn loo ṣe gun ọkọ rẹ ti wọn ṣegbeyawo papọ loṣu mẹfa sẹyin ni ọbẹ makanjẹ latari aawọ kekere kan ti wọn loo bẹ silẹ laarin wọn.

Image may contain: 1 person, closeup 
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Masallacin Murtala nipinlẹ Kano la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye lọsẹ to kọja yi.
Image may contain: one or more people
AWIKONKO rii gbọ pe ni kete ti tọkọ-tiyawo naa ti ṣegbeyawo, ni wọn lọkọ ti maa n luu Fatima, ko da a ti wọn sọ pe aludaku lo ma n fi iyawo ẹ ṣe.
Image may contain: one or more people
Ati ẹ gbọ pe ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni ọkunrin naa lu Fatima, to si mu ki oyun oṣu mẹrin to wa lara ẹ jabọ silẹ, to jẹ pe lẹyin ọsẹ meji lo too gbadun ara rẹ diẹ.

Ọkọ naa ṣi wa nibi to ti n gba itọju lọwọ bayii, bẹẹ ni Fatima ti wa lagọ ọlọpaa, nibi to ti n bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe oun fi ọbẹ naa gba ara oun kuro lọwọ ọkọ oun ni, tori pe ojoojumọ lo maa n lu oun lalubami.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI