MO GBADUN IBALOPỌ JU OUNJẸ LỌ - GBAJUGBAJA OṢERE TIATA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 16, 2019

MO GBADUN IBALOPỌ JU OUNJẸ LỌ - GBAJUGBAJA OṢERE TIATA

Gbajugbaja oṣere tiata nni, Rasheeda Tokunbo Jọlaoṣho tawọn eeyan tun mọ si Toksbaby ti sọ fawọn eeyan pe nnkan kan ṣoṣo toun ko le fi ṣere nigbesi aye oun ni ibalopọ, ati pe o yo oun ju ounjẹ lọ.

Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe ko si ipa toun ko le ko nidi iṣẹ tiata toun yan laayo, ati pe nnkan ti ko ti i jẹ koun maa ko ipa ibalopọ, ati ṣiṣi ara silẹ nihoho ni owo nla ti wọn ko tii fi lọ oun, nitori pe boun ba ri obitibiti ow, ko si nnkan to buru nibẹ.

Nibi ifọrọwerọ kan pẹluu ọkan lara awọn akọroyin ni oṣere-binrin to ṣẹṣẹ n dide bọ naa ti tu pẹẹrẹpẹerẹ ọrọ naa, to si ni bọn ba ri owo miliọnu mẹwaa dọla, ko si ipa toun ko nii ko nidi iṣẹ naa.

Bakan naa lo tun jẹ ko ye awọn eeyan pe ko tii sẹni to ṣi fi ọrọ ibalopọ lọ oun ko too di pe oun kopa ninu sinima, ati pe awọn ti wọn ti fi iru ẹ lọ ni wọn le sọ nnkan ti wọn ba pade nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI