ỌPẸ O, LẸYIN ỌJỌ MEJIDINLOGUN TO GBA IJỌBA, GOMINA ABIỌDUN YAN AKỌWE IJỌBA ATI OLORI AWỌN OṢIṢẸ GOMINA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 15, 2019

ỌPẸ O, LẸYIN ỌJỌ MEJIDINLOGUN TO GBA IJỌBA, GOMINA ABIỌDUN YAN AKỌWE IJỌBA ATI OLORI AWỌN OṢIṢẸ GOMINA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Dọkitọ Dapọ Abiọdun ti yan awọn ti yoo ṣoju ipo meji kan tawọn eeyan ti n reti latigba to ti gba ijọba lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun to kọja yi.

Awọn ti Gomina Abiọdun kede sita naa ni Ọgbẹni Ọlatokunbọ Joseph Talabi gẹgẹ bi akọwe ijọba (SSG) ati Alaaji Ṣhuaib Afọlabi Salisu gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ gomina.

Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, ọjọgbọn lawọnmeji ti Gomina Abiọdun yan yi jẹ lẹka iṣẹ ti wọn di mu, ta a si gbọ pe wọn dantọ lati di awọn ipo naa mu.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Gomina, Ọgbẹni Kunlẹ Ṣomọrin fi sita, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe Gomina Abiọdun ṣe ojuṣaaju lati yan awọn eeyan, bi ko ṣe pe itẹsiwaju ipinlẹ naa lo fi lọọ mu wọn wa.
  
A gbọ pe Talabi, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta (57) naa ni oludasilẹ ileeṣẹ Superflux International Limited ti wọn ti n tẹ oriṣiriṣi nnkan nipa eto aabo jade (security printing), to si mọ nipa agbekalẹ iṣẹ (Business Administration) daadaa.

Yatọ si pe o kẹkọọ nile-ẹkọ Citibank School of Banking to wa ni Long Island, New Yor, o tun jẹ ogbontarigi ọkan lara awọn oṣiṣẹ Guarantee Trust Bank nibi to ti di oriṣiriṣi ipo nnla-nla mu.

Alaaji Shuaib A Salisu ni ti ẹ toun jẹ olori awọn oṣiṣẹ gomina la gbọ pe o ti gba oriṣiriṣi aami ẹyẹ nla nipa eto bo ṣe n lọ ati ikansir-ẹni (information and communications)

Alaaji Ṣhuaib tawọn eeyan tun nn pe ni SAS lo ṣiṣẹ labẹ ijọba to kọja yi laarin ọdun 2011 si ọdun 2014 gẹgẹ bi igbakeji olri awọn oṣiṣẹ gomina ati olori awọn oṣiṣẹ gomina fidihẹ.

Ogbontarigi to mọ nipa imọ-ẹrọ kọmputa ni, to si lọ sile-ẹkọ fasiti tipinlẹ nibi to ti kẹkọọ gboye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI