NITORI IPO TI ỌSIBITU OOU WA NIPINLẸ OGUN, GOMINA ABIỌDUN BU SẸKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, June 10, 2019

NITORI IPO TI ỌSIBITU OOU WA NIPINLẸ OGUN, GOMINA ABIỌDUN BU SẸKUN

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Abiodun at OOUTH
Gọmina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti fọwọ sọya pe gbogbo nnkan to ba gba loun fun un lati rii pe gbogbo ọsibitu to ba wa labẹ ijọba ipinlẹ naa patapata loun mu atunṣe ati idagbasoke ba.

Ọjọ Sande ana ni Gomina Abiọdun sọrọ naa nigba to n kanminu lori ipo tawọn ọsibitu ijọba wa kaakiri ipinlẹ naa, paapaa ọsibitu awọn olukọni ti Ọlabisi Ọnabanjọ.

Nigba to n mu Gomina Abiọdun atawọn ti wọn jọ lọ bii iyawo ẹ, Arabinrin Bamidele kaakiri ọgba ọsibitu nla naa, Dọkiọ Peter Adefuye to jẹ ọgba patapata nibẹ sọ pe ọpọ nnkan lo wa nibẹ to nilo atunṣe pajawiri, ṣugbọn tawọn ko ri owo fi ṣe e.


Gomina Abiọdun sọ pe esi toun gba latọdọ awọn eleto aabo lo mu koun pinu lati lọọ fun oju lounjẹ, koun si mọ ibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ.

O jẹ ko di mimọ pe ọsibitu naa ti padanu iyi ati ẹyẹ gẹgẹ bi orukọ ẹ, to si tun jẹ ọsibitu to darajulọ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, nitori pe ọpọ awọn dọkitọ darajulọ lagbaaye lonii lo jẹ pe ọsibitu naa ni wọn gba kọja.

Nigba to n kanminu sọrọ, O sọ pe ko yẹ ko jẹ iru ọsibitu bayii ni ko nii lorukọ ati iyi mọ, tawọn eeyan yoo si maa foju tẹmbẹlu ẹ bii ọsibitu ti ko jẹ nnkankan, to si ni oun ko nii gba ko maa ri i bẹẹ lọ.

Bẹẹ lo ṣeleri pe oun yoo gbe igbimọ dide lati tubọ ṣiṣẹ iwadii kikun lori ẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI