O PARI: AWAKỌ DANFO WỌ GAU L'EKOO, LO BA BỌRA SIHOHO SALỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 14, 2019

O PARI: AWAKỌ DANFO WỌ GAU L'EKOO, LO BA BỌRA SIHOHO SALỌ

Bi ere, bi awada lawọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn lọjọ Tọside ana, nigba tọwọ awọn ọlọpaa to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, iyẹn Rapid Respond Squared rọwọ to ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni School Boy, ẹni ti wọn loo gbajumọ daadaa nidi iṣẹ Danfo wiwa.

Ohun ta a gbọ ni pe ṣe ni School Boy fi oju ọna ti ẹ silẹ, to si lọọ doju awọn mọto to n bọ lodi keji, iyẹn lagbegbe Ọpẹbi niluu Ekoo, ko to o lọọ ko sọwọ awọn ọlọpaa yii.

Bọwọ ṣe tẹ ẹ la gbọ pe o sare bọ silẹ ninu Danfo ẹ, to si n rababa bẹ awọn ọlọpaa naa, ṣugbọn tawọn yẹn yari pe afi ko foju winna ofin.

Nigba to rii pe wọn ko mu ọrọ naa ni kekere foun, ati pe wọn fẹẹ mu oun de teṣan wọn lati tii mọle, ki wọn si lọọ ṣayewo ọpọlọ ẹ gege bi ofin ṣe laa kalẹ, lo ba bọra sihoho, to si yọ boro mọ wọn lọwọ.

Ipakọ ẹ la gbọ pe awọn ọlọpaa naa atawọn eeyan to wa nibẹ n wo lọ lọọkan lasiko to n salọ.

Nibẹ ni wọn ti pe mọto ti wọn ma fi n wọ mọto, iyẹn Janwe lati wọ mọto School Boy lọ si ọgba wọn, ti wọn si n reti ẹ lati wa a kawọn pọyin rojọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI