O TAN: AFAIMỌ KI ILE ẸJỌ MA DA ẸSUN TI WỌN FI KAN OKUPE NU LỌJỌ FRAIDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, June 26, 2019

O TAN: AFAIMỌ KI ILE ẸJỌ MA DA ẸSUN TI WỌN FI KAN OKUPE NU LỌJỌ FRAIDE

Pẹluu nnkan to ṣẹlẹ nile ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Abuja lonii, o ti n foju han pe ẹsun jibiti ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn EFCC fi kan Dọkitọ Doyin Okupe lọwọ oṣelu ninu latari bi ẹlẹri kan ṣe jade lati sọ oju abẹ nikoo, to si ni ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa ko lẹsẹ nilẹ rara, tori pe kii ṣe pe o kowo ti wọn fẹsun ẹ kan an jẹ, to si ṣe e ṣe ki wọn da ẹjọ naa nu lọjọ Fraide ọtunla.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹlẹri ajọ EFCC, Shuaibu Salisu naa gan an lo tako ajọ EFCC nile ẹjọ pe loootọ loun n san miliọnu lọna ẹgbẹrun mẹwaa fun Dọkitọ Okupe to ti figba kan ri jẹ amugbalẹgbẹ Aarẹ ana, Goodluck Jonathan nipa bo ṣe n lọ, ati pe owo naa ko ni nnkan ṣe pẹlu ajọ EFCC.

Shuiabu to jẹ Oludari ẹka eto iṣuna lẹka to n ri si eto aabo (Director of Finance and Admin., ONSA) lo fidi ọrọ naa mulẹ nile ẹjọ laarọ onii pe Dọkitọ Okupe ko ni ẹṣẹ kankan nitori pe ẹsun ti wọn fi kan an ko ni nnkan ṣe pẹluu ẹ.

Ọkunrin naa sọ pe loootọ lo n gba miliọnu mẹwa loṣu ninu owo ti wọn ya sọtọ fun ọfiisi NSA ni, ati pe awọn owo naa ko ni akọsilẹ tori pe ọna tawọn owo naa gba jade ko ba ilana muu.

Oludari naa tun jẹ ko di mimọ pe oun mọ pe ki i ṣe ilana ati ofin oṣiṣẹ ni owo naa n gba jade lawọn asiko naa, ṣugbọn sibẹ, kii ṣe dandan ki awọn owo to ba n jade lati ile Aarẹ ni akọsilẹ.

Bẹẹ lo tun fi kun un pe aṣẹ lati oke ni ile-iṣẹ wọn fi n san owo naa jade lati apo NSA, bo tilẹ jẹ pe oun ko si nibẹ nigba ti Dọkitọ Okupe ati ọga agba NSA jọ ṣepade lati mọ nnkan ti wọn fẹ ẹ fi owo naa ṣe.

Ninu awijare ti ẹ, ọkan lara awọn agbẹjọro fun Dọkitọ Okupe, Tolu Babalẹyẹ jẹ ko di mimọ pe awọn owo to jade naa kii ṣe apo Dọkitọ Okupe lowo naa lọ, bi ko ṣe pe apo owo ile-iṣẹ to di mu ni wọn san owo naa si lati fi ṣe awọn nnkankan.

Onidajọ naa, I.L Ojukwu ti wa a sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yi, iyẹn ọjọ Fraide ọsẹ yii.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI