ỌMỌDUN MỌKANLELỌGBỌN DI ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ ỌYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 10, 2019

ỌMỌDUN MỌKANLELỌGBỌN DI ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ ỌYỌ

Ọla Eyitayọ, Ọyọ

"Bawo lo ṣe ri bẹẹ, ki lo ṣẹlẹ" lọrọ tí wọn lo n tẹnu pupọ ninu ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ọyọ jade nigba ti wọn gbọ pe ọmọdun mọkanlelọgbọ̀n, Ọnọrebu Adebọ Ogundoyin di abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Ọnọrebu Ogundoyin ti wọn fibo gbe wolẹ ninu idibo to kọja yi lati ṣoju agbegbe Ibarapa East nile igbimọ aṣofin la gbọ pe wọn nigba ti ọkan lára àwọn Ọnọrebu ẹgbẹ ẹ daba pe oun ni ki wọn yan gẹgẹ bi abẹnugọn ile igbimọ aṣofin kẹsan an.

Ọnọrebu Adebayọ Ọlajide toun n ṣoju agbegbe Ibadan North II lo daba naa nigba ti Ọnọrebu Adéọlá Bamidele toun n ṣoju agbegbe Isẹyin/Itẹsiwaju keji aba naa.

Ọnọrebu Ogundoyin to jade nile ẹkọ fasiti Babcock lo ti gba ipo agba naa lọwọ Ọnọrebu Michael Adeyẹmọ toun n jẹ abẹnugọn ile igbimọ aṣofin kẹjọ nipinlẹ Ọyọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI