ONI LAYẸYẸ ỌJỌ-IBI AMOSU, ALAGA ẸGBẸ AKỌROYIN NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 22, 2019

ONI LAYẸYẸ ỌJỌ-IBI AMOSU, ALAGA ẸGBẸ AKỌROYIN NIPINLẸ OGUN

Ifigbaga lawọn akọroyin kaakiri agbaye, paapaa lorilẹ-ede Naijiria n fi ikinni ayẹyẹ ọjọ ibi gbajugbaja akọroyin nni, Kọmureedi Sọji Amosu ṣe lori bo ṣe n ṣayẹyẹ ọjọ ibi ẹ lonii, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa.

AWIKONKO gbọ pe, o ti pẹ tawọn ọmọ akọroyin kaakiri orilẹ-ede yi, paapaa nipinlẹ Ogun ti n mura silẹ de ọjọ onii lati ki ọkunrin naa pẹlu bo tun ṣe jẹ alaga ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ naa.

Gbogbo awọn akọroyin patapata kaakiri ipinlẹ Ogun ati agbegbe ẹ ni wọn ti n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ọkunrin naa latigba ti aago mejila ti lu.

Ohun ta a ti ẹ gbọ ni pe awọn kan ti n fowo taaka laarin ara wọn lati mọ ẹni ti yoo kọkọ fi ikinni ranṣẹ sii, ti wọn si ti sọ fọkunrin naa pe ko gbọdọ ṣe ojuṣaaju nigba tawọn eeyan ba bẹrẹ sii ki, tori pe o gbọdọ sọ ẹni to kọkọ ki oun fun ayẹyẹ naa.

AWIKONKO gbọ pe, lati ibẹrẹ ọsẹ yi ni ẹbun ti n pe ẹbun ran niṣẹ lati fi mọ riri ọkunrin naa latari awọn ayipada to ti mu de agboole awọn akọroyin laarin asiko to di alaga, atawọn ipa manigbagbe to ti ko latigba to ti wa ninu ẹgbẹ naa.

Ọkan pataki lara awọn to n ṣagbatẹru iroyin AWIKONKO ni Kọmureedi Olusọji Amosu jẹ, ti a ko si gbọdọ gbẹyin lati dupẹ lọwọ ẹ fawọn iranlọwọ to n ṣe fun wa nile-iṣẹ yi.

Awọn kan ti ẹ ta wa lolobo pe awọn kan ti ya agbo faaji kan silẹ sibikan ti a ko tii mọ dasiko ti a kọ iroyin yi tan lati ṣayẹyẹ nla fun Sọji Amosu nitori aayo lo jẹ laarin wọn, paapaa awọn to gba tiẹ.
Ẹni to ba ri Sọji Amosu, ko ba wa sọ fun un pe gbogbo awọn alaṣẹ ati apaṣẹ ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL patapata ni wọn kii pe 'Igba ọdun, ọdun kan ni o', ati pe aṣeyi-ṣamọdun ẹ laye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI