ỌWỌ TẸ DẸJỌ ATI BUKỌLA TI WỌN N JA BAAGI GBA NIDI ATM - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Sunday, June 23, 2019

ỌWỌ TẸ DẸJỌ ATI BUKỌLA TI WỌN N JA BAAGI GBA NIDI ATM

Ọkada ni wọn lawọn ọdọmọkunrin mẹta kan fi n ja owo gba lọwọ awọn eeyan bi wọn ba ṣẹṣẹ lọọ gba owo ni Banki, iyẹn nibi ẹrọ to n pọ owo jade fawọn eeyan (ATM).

Ebenezer Olubukọla,ọmọ ọgbọn (30) ọdun ati Ọlajide Ọladẹjọ toun jẹ ọmọdun mọkandinlọgbọn la gbọ pe ọwọ ọlọpaa tẹ laarin awọn mẹta ti wọn ṣiṣẹ naa.

AWIKONKO gbọ pe Ọladẹjọ ati Bukọla pẹlu ọrẹ wọn toun ti ba ẹsẹ rẹ sọrọ ni wọn maa n duro sawọn ile ifowopamọ si lati ja owo gba lọwọ awọn to ba lọọ gba ni Banki.

Ṣugbọn ṣe la gbọ pe ori tako wọn lọjọ Tọside to kọja yi nigba ti wọn sọ pe ọga ọlọpaa Ọta lo rọwọ to wọn nigba ti iṣesi wọn mu ifura dani. Wọn bi wọn ṣe rii pe aṣiri awọn ti tu, ni wọn ti gbiyanju lati ba ẹsẹ wọn sọrọ, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ meji ninu wọn.

Ni bayii, awọn ọdaran naa ti wa ni Eleweran, to jẹ olu ileeṣẹ ọlọpaa lọdọ Kọmiṣana, ti wọn n fojoojumọ rababa fun idariji ẹsẹ wọn.

A gbọ pe ibọn AK490 pẹlu oriṣiriṣ ọta ibọn ni wọn gba lọwọ wọn loju ẹsẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI