SANWO-OLU BURA FUN AKỌWE IJỌBA ATI OLORI AWỌN OṢIṢẸ GOMINA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉThursday, June 6, 2019

SANWO-OLU BURA FUN AKỌWE IJỌBA ATI OLORI AWỌN OṢIṢẸ GOMINA

Ọlaide Ọṣinuga, Eko 

Gomina ipinlẹ Ekoo, Babjide Sanwo-Olu ti kede Arabinrin Fọlaṣade Jaji gẹgẹ bi akọwe ijọba ti yoo ba a ṣiṣẹ pọ, to si tun kede Ọgbẹni Tayọ Ayinde gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ ijọba ẹ.

Oni ni Gomina Sanwo-Olu kede sita fawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lati mọ awọn ti wọn yoo jọ tukọ ijọba ẹ fun ọdun mẹrin.

Yatọ si eyi, Gomina Sanwo-Olu tun kede Ọgbẹni Gboyega Ṣoyannwo gẹgẹ bi gbakeji olori awọn oṣiṣẹ ẹ.

Nigba to n bura fawọn eeyan naa lonii, o gbawọn nimọnran pe ki wọn lo ipo naa lati fi sin awọn araalu, ati pe ki wọn ri ipo naa gẹgẹ bi ẹni to wa a sin ilu.

Bakan naa lo tun bura fawọn akọwe agba tuntun ti ko din ni mẹfa ọtọọtọ, awọn naa ni Dọkitọ Ademuyiwa Ẹniayewun, Ọgbẹni Olumide Erinlẹ, Arabinrin Oludara Okelọla, Babs Fafunwa, Ọgbẹni Wasiu Akewuṣọla, Arabinrin Yewande Falugba ati Ọgbẹni Mustapha Oṣi-Ẹfa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI