WỌN N FI IKU WA GOMINA OKOROCHA KAAKIRI BAYII O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 1, 2019

WỌN N FI IKU WA GOMINA OKOROCHA KAAKIRI BAYII O

Okorocha, Uzodinma 
Inu ibẹrubojo ni Gomina ana nipinlẹ Imo, Rochas Okorocha wa bayii latari bi wọn ṣe lawọn agbebọn kan ti wọn fura si pe agbanipa ni wọn lọọ ka mọ ilẹ ẹ to wa ni Ogboko lagbegbe Ideato South Council, ṣugbọn ti wọn ko ri i.

Ni nnkan bi aago meji oru onii la gbọ pe awọn agbebọn naawọnu ọgba ile naa, ti wọn si da gbogbo awọn ẹṣọ inu ọgba naa dubulẹ, ti wọn fi wọ gbogbo inu ile naa.

Yatọ si pe awọn agbebọn yi lọ sile Okorocha, bẹẹ lawọn kan un lọ si ileeṣẹ redio Reach FM ti wọn gbagbọ pe Gomina ana naa lo nii, ti ọn si paṣẹ pe ki wọn dawọ iṣẹ duro.


AWIKONKO gbọ pe awọn godogodo ti wọn lọ si ileeṣẹ redio naa jẹ awọn tijọba ipinlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko fi ara wọn han, ṣugbọn ọjọ mẹta gbako ni wọn sọ pe ki wọn fi fa ileeṣẹ redio naa lulẹ.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ meji sẹyin ni wọn sọ pe ijọba tuntun nipinlẹ naa paṣẹ pe ki wọn lọọ wo ile oloke gogoro, iyẹn Akachi Tower lulẹ ti Gomina Okorocha ṣẹṣẹ ṣi.

Nigba to n sọrọ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọrlando Ikeokwu sọ pe wọn ko tii fi iṣẹlẹ naa to oun leti, ati pe lẹyin iwadii, oun yoo gbe atẹjade sita nipa ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI