IKUNLẸ ABIYAMỌ O: WỌN YIBỌN PA JOHN NILE IGBAFẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 1, 2019

IKUNLẸ ABIYAMỌ O: WỌN YIBỌN PA JOHN NILE IGBAFẸ

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Delta, Adeyinka Adeleke ti fọwọ sọya pe awọn yoo lẹpa awọn agbanipa to ṣeku pa ọdọmọkunrin kan ti wọn pe ni John Chukwudi nile igbafẹ lalẹ ana, Fraide.

AWIKONKO gbọ pe agbegbe Poli ni Oqgwashi-Uku to wa nijọba ibilẹ Aniocha South niṣẹlẹ buruku naa ti waye, nigba ti wọn sọ pe asiko ti John n gbatẹgun ninu mọto ẹ lawọn kan ti yinbọn fun un.

Ẹẹmẹfa ọtọọtọ la gbọ pe wọn yinbọn fun John lalẹ naa, to si mu kawọn to wa nitosi na papa bora, ati pe wọn lawọn agbebọn naa duro titi tẹmi fi jabọ lara ẹ ki wọn too kuro nibẹ.

-----------------------------------------------------@@@@@@@@@@@@------------------------------------------------------------------ Ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL lo n gbe IROYIN AWIKONKO jade pẹlu ontẹ Ijọba orilẹ-ede Naijiria labẹ ajọ iforukọsilẹ, iyẹn CORPORATE AFFAIRS COMMISSION.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI