AFCON2019: ITAN TẸNIKẸNI KO LE FI BALẸ LA FẸ Ẹ FI BALẸ - AKỌNIMỌỌGBA ALGERIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, July 8, 2019

AFCON2019: ITAN TẸNIKẸNI KO LE FI BALẸ LA FẸ Ẹ FI BALẸ - AKỌNIMỌỌGBA ALGERIA

Akọnimọn-ọngba ẹgbẹ agbabọọlu ti orilẹ-ede Algeria, Djamel Belmadi ti sọ pe itan tẹnikẹni ko tii fi balẹ ri lawọn fẹẹ fi balẹ ninu idije bọọlu ilẹ adulawọ, iyẹn African Cup of Nations to n lọ lọwọ lorilẹ-ede Egypt.

O tun sọ pe ko si nnkan to ni ki orilẹ-ede Algeria ma gba ife ẹyẹ AFCON tọdun yi tori pe awọn ti gbaradi gidigidi, tawọn si ti mura lati koju eyikeyi ẹgbẹ agbaọọlu to ba wa a ba wọn ninu idije to n lọ lọwọ naa.

Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe bi wọn ba ṣe gbe e wa lawọn yoo ṣe koju wọn, nitori tawọn ko bẹru ẹgbẹ agbabọọlu kankan nitori pe lati ọdun 1990 lawọn ti n foju sọna fun ife ẹyẹ naa.

Fawọn to ba n ba idije AFCON2019 lọ, wọn yoo mọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Algeria gbo omi ewuro soju akẹgbẹ wọn, iyẹn Guinea pẹluu aami ayo mẹta si odo lọjọ Aiku ana, eyi gan an lo fun akọnimọn-ọngba naa ni igboya lati sọrọ yi jade.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI