AHMẸD ATAWỌN ỌRẸ Ẹ FIPA BỌMỌDUN MẸRINLA SUN, WỌN FA IDI RẸ YA PẸRẸPẸRẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 6, 2019

AHMẸD ATAWỌN ỌRẸ Ẹ FIPA BỌMỌDUN MẸRINLA SUN, WỌN FA IDI RẸ YA PẸRẸPẸRẸ

"Ẹ foju aanu wo wa, iṣẹ eṣu ni" lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu awọn gendekunrin mẹta kan, ti wọn fẹsun kan pe wọn fipa ba ọmọdebinrin, ọmọdun mẹrinla kan sun lagbegbe Maitumbi, Minna jade nigba tọwọ ọlọpaa tẹ wọn.

Abdulrahman Ahmed, ọmọdun mọkandinlogun; Isyaku Umar, ọmọ ogun ọdun ati Adamu Sani toun naa jẹ ọmọ ogun ọdun la gbọ pe wọn dọdẹ ọmọdebinrin naa ta a forukọ bo laṣiri, ki wọn too muu wọ ile akọku kan, ti wọn si fa a nidi ya pẹrẹpẹrẹ.

Ohun ta a agbọ ni pe, ọmọ naa lo sunkun lọ ọ bawọn obi rẹ, to si ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ fun wọn, idi ni yii ti wọn fi gba tẹṣan ọlọpaa lọ lati lọọ fọrọ naa to wọn leti. Loju ẹsẹ la gbọ pe awọn ọlọpaa ti gbera, ti wọn si wa awọn ọdaran mẹtẹẹta naa kan.
 
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, Ọgbẹni Mohammed Abubakar sọ pe asiko ti wọn ran ọmọ naa niṣẹ lawọn ọdaran naa fipa gbe e wọle akọku kan, ti wọn si muna gidi labẹ ẹ.

O wa a fidi ẹ mulẹ awọn ti n gbero lati foju awọn ọdaran naa bale ẹjọ lọsẹ to m bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI