AISI ETO AABO: ASIKO TI TO LATI ṢE APERO APAPỌ LORILẸEDE NAIJIRIA - GOMINA ỌRTỌM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 20, 2019

AISI ETO AABO: ASIKO TI TO LATI ṢE APERO APAPỌ LORILẸEDE NAIJIRIA - GOMINA ỌRTỌM

Gomina ipinlẹ Benue, Samuẹl Ọrtọm ti pariwo sita lonii Satide pe pẹluu bi aisi eto aabo ṣe n gba gbogbo orilẹede Naijiria lasiko yi, o ti to gbedeke  ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo pe apero apapọ lati mọ ọna abayọ sawọn kudiẹ-kudiẹ.

O ni ninu apero naa ni ki wọn ti faaye silẹ fun gbogbo ọmọ orilẹede yi lati sọ awọn iṣoro to n koju wọn, ki wọn si sọ awọn ọna abayọ ti onikaluku wọn ba mọ, ki alaafia ati iṣọkan le tubọ jọba.

Gomina Ọrtọm lo n sọrọ naa lasiko to n gba Aarẹ Ṣọọṣi ECWA, iyẹn Evangelical Church Winning All, Rẹfurẹndi Stephen Panya Baba lalejo nile Gomina to wa niluu Makurdi laarọ oni, Abamẹta
O yẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari pe apero apapọ "National Dialogue Forum" nibi ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo ti sọ awọn nnkan to n koju wọn, paapaa lẹka eto aabo, ki wọn si wa ọna abayọ sii.
Nibẹ lo tun ti bu ẹnu atẹ lu aṣẹ ti Kautal Hore ti ẹgbẹ miyetti Allah gbe sita fawọn eeyan pe ki wọn ja lati gba ara wọn silẹ lọwọ awọn to ba fẹẹ koju wọn. O ni aṣẹ naa jẹ eyi to n da ogun nla airotẹlẹ silẹ, ati pe o ṣeni laanu pe iru ẹgbẹ bẹẹ yoo ma a sọ awọn ọrọ to n da wahala silẹ, ti ijọba apapọ ko si nii pe wọn lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI