AWỌN EEYAN ṢI N SỌRỌ LORI IGBEYAWO AWỌN ARUGBO YII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 8, 2019

AWỌN EEYAN ṢI N SỌRỌ LORI IGBEYAWO AWỌN ARUGBO YII

Orin 'tun mi gbe, ọkọ mi tun mi yan' ni wọn n kan fun iya arugbo, ẹni ọdun mẹtalelọgọta kan nipinlẹ Zaria lai pẹ yi pẹlu boun ati ololufẹ rẹ ṣe ṣe igbeyawo alarinrin.

Photos: 73 year old man weds his 63 lover in Kaduna 
Kaakiri ori ayelujara lawọn to gbọ si ohun to ṣẹlẹ ti n fi ṣe ọrọ sọ, ti wọn si n sọ pe ko si'gba ta a daṣọ, ti a ko rẹni wọ ọ, ati pe ko si nnkan ti ko le ṣẹlẹ labẹ ọrun ti a wa yii.

Photos: 73 year old man weds his 63 lover in Kaduna 
Ẹnikan ti wọn pe ni Chinecherem Ebubechi lo gbe fọto awọn ololufẹ meji naa sori ikanni ayelujara ti Facebook, pe baba agbalagba ẹni ọdun mẹtalelaadọrin (73) kan, Matthew Owojaiye ti wọn tun sọ pe Ajihinrere ni lo gbe mama agbalagba naa Abọsẹde Ayọbọla niyawo.

Photos: 73 year old man weds his 63 lover in Kaduna 
Ohun to n jẹ kayeefi, to mu kawọn eeyan maa sọrọ lori igbeyawo naa ni bi wọn 'se sọ pe ni nnkan bi aadọta ọdun sẹyin ni Baba naa ti kẹnu ifẹ si mama yi, ṣugbọn to sọ pe oun ko ṣe, ṣugbọn nigba tawọn mejeeji tun maa pade ara wọn, iyalẹnu lo jẹ pe awọn mejeeji ko tii ni ololufẹ.

Photos: 73 year old man weds his 63 lover in Kaduna 
Eyi lo jẹ ki mama yi tun pada gba lati fẹ ẹni to ti kẹnu ifẹ sii lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Photos: 73 year old man weds his 63 lover in Kaduna 
Ṣọọṣi Baba Oyedepo, iyẹn Living Faith to wa nipinlẹ Zaria ni wọn ti ṣegbeyawo naa pẹluu mọlẹbi, ọrẹ atawọn abaniyọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI