AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN YINBỌN PA HALIM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 20, 2019

AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN YINBỌN PA HALIM

Ṣe lọrọ di boolọ o yago lati bi ọjọ mẹrin sẹyin lagbegbe Ibusa nipinlẹ Delta nigba ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kọju ija sira wọn, ti wọn si bẹrẹ sii fi iku wa ara wọn kaakiri.

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Vikings ati Ẹyẹ la gbọ pe wọn fi agbara han ara wọn lati bi ọsẹ meji sẹyin, ṣugbọn ti ọrọ tun bẹyin yọ lọna ara.

 
Ṣadede ni wọn sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yinbọn pa gendekunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Fabian Halim ti wọn tun n pe ni Fabio. A gbọ pe iyalẹnu lo n jẹ fawọn to mọ Fabio nigba ti wọn gbọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI