BAṢIRU ATI ADEKỌLA TI HA O, ORI OKU NI WỌN N GE TA KAAKIRI ILUU IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 13, 2019

BAṢIRU ATI ADEKỌLA TI HA O, ORI OKU NI WỌN N GE TA KAAKIRI ILUU IBADAN

Boroboro lawọn baale ile meji kan ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn lọ maa ge ori oku kaakiri ipinlẹ Ọyọ ta n ka lọgba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lọjọ Ẹti ana lẹyin tọwọ palaba wọn segi.

Baṣiru Abdullahi ati Martin Adekọla la gbọ pe ọmọ bibi iluu Ọja Funi to wa niluu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun lawọn mejeeji.
 
Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ, Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ṣina Olukọlu sọ pe ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ Ọjọbọ lọwọ tẹ awọn ọdaran naa lagbegbe Ikoyi Ile si Ogbomọṣọ pẹluu ori oku meji.

O ni awọn mejeeji fẹẹ le na papa bora lasiko ti akara wọn tu sepo ṣugbọn ti okete wọn ko ri aaye boru mọ ọlọdẹ lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI