Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Naijiria to ti fẹyinti tipẹ, Ṣẹgun Ọdẹgbami ti sọ pe ifigagbaga to fẹẹ waye lonii Aiku laarin ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Algeria ati Super Eagles ko nii rọrun rara, nitori pe ifigagbaga nla ti yoo mi gbogbo agbaye titi ni.
Oni ni Ṣẹgun Ọdẹgbami sọrọ naa jade niluu Ọta, ipinlẹ Ogun, to si ni bawọn Super Eagles ko ba mura daadaa lati kọju awọn alatako wọn, afaimọ ko ma jẹ pe itiju nla ni wọn yoo mu bọ, toun ko si gba a ladura bẹẹ fun wọn.
O jẹ ko di mimọ pe bawọn Super Eagles ba fẹẹ ṣe aṣeyọri, a fi ki wọn gbọnran si akọnimọngba wọn lẹnu, ki wọn si tẹle gbogbo awọn ofin to ba la kalẹ fun wọn.
Bẹẹ lo tun tẹnumọ ọrọ rẹ pe bawọn ṣe na ikọ Desert Foxes ti orilẹede Algeria lọdun 1980 pẹluu aami ayo mẹta si oodo gbọdọ jẹ eyi ti yoo wu wọn lori, ki wọn si le tayọ.
No comments:
Post a Comment