KAYEEFI NLA: Ẹ WO JIMMY TO LO ỌJỌ MARUN GBAKO LORI ṢALANGA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 16, 2019

KAYEEFI NLA: Ẹ WO JIMMY TO LO ỌJỌ MARUN GBAKO LORI ṢALANGA

Ọmọ orilẹede Belgium tun ti fi itan tuntun balẹ lagbaye bayii, pẹluu bo ṣe lo ọjọ marun un gbako lori ṣalanga lai dide lọ sibi kankan.

Image result for The Man That Spent Almost Five Days On A Toilet 
Ọmọdun mejidinlaadọta ni wọn pe ọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Jimmy De Frenne, ti orukọ rẹ si tun ti pada wọ iwe itan agbaye, iyẹn Guinness Book of Record leekeji.

 
Ọdun 2016 ni Jimmy De Frenne kọkọ fitan balẹ nigba to lo wakati mejilelọgọrin (82hours) nibi to ti n lọ aṣọ lai kuro loju kan, to si jẹ pe ko tii sẹni to ṣe iru ẹ ri.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, kii ṣe pe Jimmy De Frenne dee de pinu lati tun fitan balẹ, bi ko ṣe pe iroyin kan to gbọ nipa ọkunrin kan ti wọn loo lo ọgọrun wakati lori itẹ lai dide, ti ko tii ṣeni to ṣe nnkan to jọ bẹẹ ri, ko da, ti ẹnikẹni ko tun le itan naa ba.

 
De Frenne lo pinu pe oun fẹẹ le ẹni naa ba, to si mu ko gba ile igbọnsẹ gbogboogbo kan ti wọn ti n gbafẹ, iyẹn Filip's Place Bar to wa ni Ostend lọ lọsẹ to kọja yi, to si lọọ sọ nnkan toun fẹ ẹ ṣe nibẹ fun wọn pe oun fẹẹ lo wakati 168 lori ijokoo ṣalanga.

Ori ijokoo yi la gbọ pe wọn ti n gbe ounjẹ wa fun un, titi to fi lo wakati 116, eyi to jẹ ọjọ marun un gbako nigba ti ẹmi rẹ ko fẹẹ gbe e mọ, ko too dide.

 
Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ lori idi ti ko fi lo ọsẹ kan to ṣadehun rẹ, o sọ pe "O ti rẹ mi ni, ati pe gbogbo ẹsẹ lo n dun mi, ṣugbọn mo nigbagbọ ninu aṣeyọri mi, eyi lo mu ki n jẹ ki gbogbo agbaye mọ nipa nnkan ti mo ṣe yi. Mo dupẹ lọwọ awọn to duro ti mi, bo tilẹ jẹ pe ko dun mọ mi ninu pe mi o le pari ọsẹ kan ti mọ fẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI