NITORI ẸSUN YAHOO, WỌN JU ỌMỌ OGUN SẸWỌN N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, July 4, 2019

NITORI ẸSUN YAHOO, WỌN JU ỌMỌ OGUN SẸWỌN N'IBADAN

Oṣu mẹta gbako ni ọdọmọkunrin, ọmọ ogun ọdun kan ti wọn pe orukẹ ni Quadri Sulaimọn Ayọbami yoo lo lẹwọn bayii pẹlu bi ile ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Ibadan, ipimlẹ Ọyọ lana Wẹside ṣe gbe idajọ kalẹ.

Onidajọ Patricia Ajoku lo gbe idajọ naa kalẹ fun akẹkọ ile ẹkọ gbogboniṣe Oke Ogun to wa ni Ṣaki latari ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an pe o n lu jibiti ori ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo, eyi ti wọn loo tako ofin lilo ayelujara tọdun 2015.

A gbọ pe ọjọ kẹrindinọgbọn ni ajọ EFCC kọkọ foju Quadri bale ẹjọ, ti wọn si fẹsun marun ọtoọọtọ kan an, eyi to sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun naa pẹluu alaye, ti wọn si pada din awọn ẹsun naa ku.

Wọn ni ṣe ni Quadri n lo orukọ olorukọ, iyẹn Kate Linda latimaa fi lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara, to si tun ni ayelujara ti wọn fi n ranṣẹ iyẹn [email protected] Orukọ yi ni wọn lo fi lu ẹni kan ti wọn pe ni Kenneth Stroud ni jibiti obitibiti owo.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI