WỌN DANA SUN GBAJUMỌ AGBẸJỌRO NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, July 1, 2019

WỌN DANA SUN GBAJUMỌ AGBẸJỌRO NITA GBANGBA

Adura ti ọpọ awọn obi ko gbọdọ panumọ lati ṣe 'AMIN'si ni pe wọn ko nii bi ọmọ ti yoo ran wọn lọ sọrun apapandodo. Eyi lo lọ nibamu pẹluu bi awọn ọmọdebinrin ati ọmọdekunrin kan ṣe dana sun iya-iya wọn lọsan gangan.

Iya ti wọn dana sun yi, Arabinrin Veronica Okwuogu, ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin (66) la gbọ pe gbajugba agbẹjọro ni niluu Akwa, ipinlẹ Anambra.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni iya veronica lo ri awọn ọmọ-ọmọ ẹ meji ti wọn n ba ara wọn sun ninu yara, eyi ni wọn loo muu pariwo sita pe oun yoo fi iya nla ti wọn ko nii gbagbe nigbesi aye wọn jẹ wọn.

Awọn ọmọ yi la gbọ pe ile ẹkọ girama ni wọn ṣi wa, ati pe orilẹ-ede South Afrika ni mama wọn wa, nibi to ti lọ ọ gbafẹ fungba diẹ. Wọn ni bawọn ọmọ yi ti wọn forukọ laṣiri ṣe rii pe aṣiri awọn ti tu, ati pe o ṣee ṣe ki nnkan ti Veronica fẹẹ ṣe fun ju nnkan ti wọn ko lero lọ.

Eyi ni wọn loo mu kawọn ọmọ naa raga bo Veronica mọlẹ, ti wọn si fi okun de e, ki wọn to bẹrẹ sii maa luu. Nigba ti wọn lu daadaa la gbọ pe wọn wọ sita gbangba, ti wọn si ju ina sii lara.

Kawọn araadugbo to o mọ nnkan to n ṣẹlẹ, wọn ni Veronica ti ku, o si ti jona kọja afẹnusọ. Loju ẹsẹ lawọn araadugbo ti ranṣẹ sawọn ọlọpaa lati wa a wo nnkan to n ṣẹlẹ, taa si gbọ pe ọgba ọlọpaa lawọn ọmọ naa wa dasiko yi.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Mohammed Haruna bo tilẹ jẹ pe loootọ ni eeyan jona, ṣugbọn tawọn ko le sọ pataki nnkan to ṣokun fa ina naa.

O lawọn ti gbe oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu Regina Caeli fun ayẹwo, ati pe iwadii ṣi n lọ lọwọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI