ONI LAYẸYẸ ỌJỌ IBI GBAJUMỌ ONIROYIN, ARABINRIN DERIN SALAWU, Ẹ BA WA KI WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 1, 2019

ONI LAYẸYẸ ỌJỌ IBI GBAJUMỌ ONIROYIN, ARABINRIN DERIN SALAWU, Ẹ BA WA KI WỌN

Ọkan pataki ni Arabinrin Aderinsọla Salawu jẹ lawujọ awọn oniroyin nipinlẹ Ogun, paapaa lorilẹ-ede Naijiria, to si tun jẹ pataki ninu awọn to n ṣagbatẹru Iroyin AWIKONKO kaakiri orilẹ-ede Naijiria, ti a ko si le pa a mọra lati fi ẹmi imoore han sii.

Yoruba bọ, wọn ni yinni-yinni kẹni o ṣe min in lo mu ka lo anfaani ayẹyẹ ọjọ ti Arabinrin Derin Salawu lati fi dupẹ gidigidi lọwọ rẹ fun bo ṣe n ran ile iṣẹ wa lọwọ lati gbe wa larugẹ.

Oni tii ṣe ọjọ kinni oṣu keje ni ayajọ ọjọ ti Obinrin naa de ile aye, to si jẹ pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oniroyin kaakiri agbaye, paapaa lorilẹ-ede Naijiria ni wọn ti n fi atẹjiṣẹ ati ẹbun oriṣiriṣi ranṣe sii.

A n fi asiko yi sọ pe igba ọdun, ọdun kan ni o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI