YAHOO-YAHOO: WỌN TUN JU ỌLABỌDE SẸWỌN N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 16, 2019

YAHOO-YAHOO: WỌN TUN JU ỌLABỌDE SẸWỌN N'IBADAN

Oṣu mẹrin gbako ni ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlogun kan, Ọlabọde Ọyarẹmi yoo lo lẹwọn lati jiya ẹṣẹ jibiti ti wọn lo n lu lori ayelujara pẹlu orukọ oyinbo kan ti wọn pe ni Angelina Kimberly, to tun sọ pe nọọsi loun.

Wọn ni ọpọ eeyan, paapaa awọn oyinbo ni Ọlabọde ti forukọ Angelina naa lu, pẹlu imeeli [email protected]. Ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun yi la gbọ pe aṣiri Ọlabọde ti wọn ni ileẹkọ giga gbogbniṣe tiluu Ibadan tu sọwọ ajọ EFCC lagbegbe Kọlapọ Iṣọla, Akobo niluu Ibadan.

Latigba naa la ti gbọ pe awọn EFCC ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, ko to o di pe wọn foju ẹ bale ẹjọ, ti idajọ si waye lana an ọjọ Aje, tii ṣe Mọnde.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ fun Ọlabọde, Onidajọ Patricia Ajoku tile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ibadan sọ pe awọn ẹsun ti wọn fi kan ọmọ Yahoo naa tako iwe ofin ọdaran ti ayelujara apa kejillogun abala keji tọdun 2015.

Bo tilẹ jẹ pe Ọlabọde gba kamu pe loootọ loun jẹbi, eyi lo mu ki agbẹjọro EFCC, Ṣanusi Galadanchi baa bẹbẹ pe kile ẹjọ foju aanu wo o, ki wọn si ba a din idajọ naa ku ni rampẹ.

Eyi lo mu ki Onidajọ naa sọ pe ki Ọlabọde lọọ gbatẹgun oṣu mẹrin pere lọgba ẹwọn, ko si da owo ti ko din lẹgbẹrun mẹta aabọ dọla ($3,600) to lu jibiti ẹ pada si apo ijọba apapọ.

Bẹẹ ni yoo tun gbagbe awọn nnkan ti wọn gba lọwọ ẹ bii ẹrọ kọmputa alagbeeka Apple ati Tọṣhiba, foonu Samsung Galaxy Luna Pro, iPhone, Nokia phone, aago Apple, ati Smile 4G ti wọn fi n wọ ayelujara (internet modem).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI