EYI NI AṢIRI BI WỌN ṢE TAN ISMAILA PA LỌJỌ ỌDUN ILEYA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 19, 2019

EYI NI AṢIRI BI WỌN ṢE TAN ISMAILA PA LỌJỌ ỌDUN ILEYA

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan niku ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Ismaila Ogunṣọla ṣi n jẹ kayeefi fawọn eeyan, paapaa awọn araalu Owode Ẹgba, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi/Owode, ipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe sọ pe ọjọ idun Ileya to kọja yi ni wọn pe e, to si jẹ pe nigba ti wọn maa pada ri, oku ẹ ni wọn ri.

Ki i ṣe pe bi Ismaila ti wọn loo fi ọdun meje gbako kọ iṣẹ telọ ṣe ku lo n jẹ kayeefi fun gbogbo eeyan, paapaa awọn ara agbegbe Owode, bi ko ṣe bi wọn ṣe ba oku ẹ lori igi Mango, ti wọn tun de e lapa ati ẹsẹ, ti wọn si tun sokun mọn ọn lọrun gan an lo n jẹ ẹdun ọkan fawọn araalu, paapaa awọn ẹbi rẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, won ni ọdun meji sẹyin ni wọn sọ pe Ismaila gba aaye lọdọ ọga rẹ to kọ ọ niṣẹ telọ, iyẹn Ọgbẹni Sulaimọn Abisoye niluu Owode Egba lati fi wa owo ti yoo fi ṣe firidọọmu, idi ni yii ti wọn loo fi wa ibi to ti n ṣiṣẹ lọgba ọsin (poultry) kan to wa lagbegbe Malaaka, opopona Adejọin, Owode kan ni nnkan bi oṣu mẹsan sẹyin.

Wọn ni latigba ti Ismaila ti de ileeṣẹ nnkan ọsin naa ni kii tii gba owo oṣu rẹ pe, nitori ti wọn sọ pe gbogbo igba ni ọga wọn to ni ibẹ kii fun wọn lowo ni gbogbo igba, ta a si gbọ pe o le lowo oṣu meji ti ọga naa jẹ Ismaila, ko too ku.

AWIKONKO gbọ pe ọsẹ meji sẹyin ni Ismaila pe ọrẹ rẹ kan, to maa n fọrọ lọ, to si loun la ala kan pe wọn fẹẹ ya oun ni were ojiji, nitori naa, oun yoo kuro l'ọgba nnkan ọsin toun ti n ṣiṣẹ, paapaa bi iwa ọga wọn tun ṣe ri, ati bi kii ṣe e fun wọn lowo oṣu nigba gbogbo.

Idi ni yii ti wọn loo fi sọ pe oun yoo sọ fun ọga oun naa pe ara baba oun ko ya, nitori naa oun ko nii wa fawọn asiko kan lati tọju baba oun, ati pe oun nilo owo lati fi tọju baba oun, ti wọn ni ọga naa sọ fun un pe ko buru.

Ọjọ Sande ọsẹ to kọja yi, to jẹ ọjọ ti gbogbo awọn Musulumi lagbaaye n ṣayẹyẹ ọdun Ileya, iyẹn ni nnkan bi aago mẹjọ ku iṣẹju meloo kan la gbọ pe ọga Ismaila, Ọgbẹni Ṣẹgun Adekọya pe e lori foonu pe ko wa a gba owo ẹ to ku lọwọ oun, ati pe o lawọn iṣẹ kan ti yoo ba oun ṣe.

Ohun ta a gbọ ni pe ibi ti Ismaila ti n ran aṣọ to ti gba lọwọ ni ọga rẹ naa ti pe e, ti wọn ni loju ẹsẹ lo ti fi aṣọ naa silẹ, lati lọ. Bo ṣe fẹẹ jade la gbọ pe o sọ fun baba, iya, egbọn re kan, ati ọrẹ rẹ ti wọn ni wọn jọ sunmọ ara wọn pe ọga oun pe oun pe koun wa a gba owo kan to jẹ oun, to si pa gbogbo aṣọ to n ran lọwọ ti, lero wi pe oun ko ni pẹ ẹ de.

Iyalẹnu lo jẹ pe titi tilẹ ọjọ naa fi ṣu ni wọn ko fi ri Ismaila ko pada wa sile, to si jẹ pe gbogbo bi wọn ṣe n pe foonu ẹ ni ko gbe e, igba to ya ni wọn sọ pe foonu naa ko lo mọ, eyi ni wọn lo mu ifura dani, nitori ti wọn sọ pe Ismaila kii rin irin kurin, kii si i fọrọ ẹ bo fẹnikẹni to ba sunmọ ọn.

Aarọ ọjọ keji tii ṣe Mọnde ọsẹ to kọja yi la gbọ pe mama Ismaila gbera lati lo sibi ti Ismaila ti n sise, ti won si so pe won ba ore re ti won jo n sise, iyen Sulaimon, toun funra re si so pe looto ni Ismaila wa sinu ogba naa, ko da tawon tun jo dapaara ko too lo sun sinu yara, sugbon iyalenu lo je pe oun ko ri mo nigba to to asiko kan, toun si ro pe boya o ti fo fensi jade sita lai je koun mo.

Igba ti wọn ni wọn ko ri Ismaila ni wọn ni ẹgbọn rẹ, Wasiu Ogunṣọla atawọn kan tun gbera lati lọ sibẹ lati lọ mọ nnkan to n ṣẹlẹ, to si jẹ pe nigba ti wọn maa de bẹ, wọn ko ri Ismaila, idi ni yii ti wọn fi gba teṣan ọlọpaa Owode lọ lati lọọ fọrọ naa to wọn leti, ti wọn si ni iyalẹnu lo jẹ pe wọn ti gba ọga Ismaila nibẹ, to ti n kọ ọrọ silẹ.

Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti ti ọga Ismaila mọleẹ ati Sulaimọn mọlẹ, tawọn mejeeji si sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa, ti wọn si lawọn ọlọpaa bẹrẹ igbesẹ lati ṣewadi. Ṣugbọn iyalẹnu ni wọn loo jẹ pe ṣe lawọn ọlọpaa Owode tun gbabọdi, ti wọn si fẹ maa lo ọgbọn arekereke lati pana ọrọ naa mọlẹ, paapaa ti wọn tun n fẹsun kan awọn mọlẹbi Ismaila pe awọn ni wọn gbe ọmọ wọn pamọ lati fi gba owo lọwọ ọga Ismaila, iyẹn Ọgbẹni.

Idi ni yii ti wọn lawọn mọlẹbi Ismaila fi gba olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran lọ lati lọọ fọrọ naa to wọn leti lọjọ Wẹside, tawọn yẹn si sọ pe awọn bẹrẹ igbesẹ lọjọ Tọside. Ọsan ọjọ Tọside la gbọ pe awọn ọlọpaa lati Eleweran gba ilu Owode lọ lati lọọ ṣewadi, ti wọn si wa gbogbo inu ọgba ọsin (poultry) naa ti wọn loo fi diẹ le ni eeka marun (5 acres) ko too di pe wọn kofiri ẹnikan lori igi Mango.

Ṣe lọrọ di boolo o yago nigba ti ẹni ti wọn ba lori igi naa jẹ oku Ismaila. Iyalẹnu ni wọn loo jẹ pe wọn ti ṣọ ọ lọwọ ati ẹsẹ, ko da, ti wọn tun ba okun lọrun ẹ, to ti n jẹra pẹluu idin lara. Loju ẹsẹ ni wọn ti sọ oku ẹ kalẹ.


Nigba to n sọrọ, ẹgbọn Ismaila, Ọgbẹni Wasiu Mukaila Ogunṣọla “Mi o si nile lọjọ ọdun Ileya yẹn, ọjọ keji ọdun ni wọn pe mi lori foonu pe wọn ko ri, mo ki mama ẹ lọ sibi to ti n ṣiṣẹ, tori pe ọmọ Baba mi ni, iya ọtọọọtọ lo bi wa. Igba ti wọn de bẹ, wọn lawọn kan geeti, wọn ko ri ẹnikankan. Ko pẹ ni wọn tun pe mi pe awọn ti ri ẹnikan nibe to sọ pe loootọ ni Ismaila wa sinu ọgba, ṣugbọn ti wọn ko mọ bo ṣe jade tori pe wọn maa n ti geeti ọgba yẹn ni.



“Igba ti mo de ni mo gba nọmba ọga Ismaila, ti mo si pe e lori foonu pe ko jẹ ka pade ni teṣan ọlọpaa Owode lati wa Ismaila, to si loun naa ko si nile, nigba ta a fi maa pade, teṣan ọlọpaa la ti ba a, to n bawọn ọlọpaa sọrọ pe a parọ mọ oun lati fi aburo wa gba owo lọwọ ọga ẹ. Idi ni yii ta a fi lọ si Eleweran lati lọ fi to wọn leti.



“Iyalẹnu lo jẹ fun wa nigba ti a ri oku aburo mi lori igi Mango, to si loun ko mọ nnkankan nipa iku ẹ, ati pe wọn ni kii sẹni to le wọnu ọgba naa, tori pe ṣe ni wọn ṣe fẹnsi ẹ ga ju nnkan teeyan le pọn lai lo akaba. Mo fẹ kawọn ọmọ Naijiria gba wa lo jẹ ka fi to ẹyin oniroyin leti o.”



Ọrẹ Ismaila to sunmọ, Ọbasan Temitọpe sọ pe “Ọsẹ meji sẹyin ni Ismaila pe mi, to sọ pe oun la ala pe wọn fẹẹ ya oun ni were. O ma n sọrọ ẹ fun mi daadaa, emi naa si ma n sọ temi fun. O loun fẹẹ kuro nibẹ pe oun fẹẹ gba owo oun koun too kuro nibẹ. Ọjọ Sande to lọ lọhun, iyẹn ọjọ kẹrin oṣu yi lo sọ pe ọga oun sọ pe ere ori igi ni oun fẹẹ ṣe lati sọ pe ara baba ẹ ko ya, nitori toun mọ pe irọ ni Ismaila n sọ.



“Aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹdogun lo pe mi lọjọ ọdun Ileya pe ọga oun pe oun pe koun wa gba owo, o ma n sọ pe ọga oun ko mọ riri nnkan toun n ba a ṣe. Ọrọ naa ko ye mi rara. Kawọn ọmọ Naijiria ba wa da si.”


Irọlẹ ọjọ Fraide la gbọ pe wọn pada sin oku Ismaila. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fidi ẹ mulẹ, to si lawọn ti mu awọn min in lori iṣẹlẹ.

Laarọ oni Mọnde la tun gbọ pe wọn ti fi ọga Ismaila silẹ lahamọ, bẹẹ ni Sulaimọn ṣi wa lahamọ ni tiẹ, tori ti wọn loun ni afurasi bayii, ṣugbọn ti iwadii ṣi n lọ lọwọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI