IKUNLẸ ABIYAMỌ O, ỌWỌ TẸ ỌMỌ YAHOO MỌKANDINLỌGBỌN N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 8, 2019

IKUNLẸ ABIYAMỌ O, ỌWỌ TẸ ỌMỌ YAHOO MỌKANDINLỌGBỌN N'IBADAN

Lọjọ Wẹside ana ni ileeṣẹ ajọ to n ri ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tiluu Ibadan nipinlẹ Ọyọ tun kede sita pe ko din ni mọkandinlọgbọn lawọn gendekunrin ti wọn ko niṣe meji ju jibiti ori ayelujara tọwọ tẹ lọ.

 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Akoto Estate, Ẹlẹbu niluu Ibadan lọwọ palaba wọn ti segi laarọ kutu ana latari olobo ti wọn lawọn kan ti fura si awọn eeyan naa ta ileeṣẹ EFCC laipẹ yii, ta a si gbọ pe o niye ọjọ ti wọn fi tọpinpin wọn, ki wọn too lọ ko wọn.

Lara awọn nnkan ti a gbọ pe wọn gba lọwọ wọn ni mọto nla bọginni mẹjọ ọtọọtọ, foonu olowo nla loriṣiriṣi ati ẹrọ kọmputa laagbeeka, to fi mọ awọn ayederu iwe ti wọn fi n lu jibiti.

 
A gbọ pe ajọ naa ti fidi ẹ mulẹ pe ko nii pe tawọn eeyan naa yoo fi foju bale ẹjọ, to si ṣee ṣe kawọn ti wọn ba rii pe wọn ko mọn ọn nnkankan ninu wọn gba idalere. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI