KO TII TO ASIKO LATI BU ẸNU ATẸ LU IJỌBA DAPỌ ABIỌDUN O - ỌNỌREBU OYEDEJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉTuesday, August 6, 2019

KO TII TO ASIKO LATI BU ẸNU ATẸ LU IJỌBA DAPỌ ABIỌDUN O - ỌNỌREBU OYEDEJI

Olori ọmọ ile igbimọ aṣofin to kere julọ nipinlẹ Ọgun, Ọnọrebu Ganiyu Alani Oyedeji ti parọwa fawọn araalu pe o ti ya ju lati maa bu ẹnu atẹ lu ijọba Gomina ipinlẹ Ogun., Ọmọba Dapọ Abiọdun nitori pe igbesẹ lati le ṣe aṣeyọri ni wọn n gbe lọwọ.

Ọnọrebu Ganiyu Oyedeji to n ṣoju ẹkun Ifọ keji nile igbimọ aṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM lo sọrọ naa lasiko to n b'AWIKONKO sọrọ laipẹ yi niluu Abẹokuta, nibẹ lo ti sọ pe gbogbo igbimọ ti Gomina Abiọdun n yan ni lati le jẹ ki aṣeyọri to lọọrin jọba ninu ijọba naa ni.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Bi wọn ba n sọ pe Gomina Dapọ Abiọdun n yan igbimọ nibi ati lọhun, o to bẹẹ, o ju bẹẹ lọ, nitori pe aṣeyọri nijọba n wa, ati lati le jẹ ki alaafia jọba laarin gbogbo ẹya patapata to wa nipinlẹ Ogun.

"Ọrọ nipa Gomina wa nipa awọn nnkan ti wọn n ṣe yi, paapaa nipa ohun tawọn araalu le maa sọ, o ti ya ju lati maa sọ pe wọn ko tii bẹrẹ ohunkohun, oṣu kẹta la ṣi le sọ pe ijọba yi n lo lọ. O dami loju pe bi wọn ṣe rii si ni wọn ṣe n sọ ọ, ṣugbọn ko ri bẹẹ.

"Bi ẹ ba si wo o, ẹ ma rii pe ko tii si Kọmiṣana, awọn amugbalẹgbẹ ni wọn ṣi n dari ẹka ijọba. Ijọba yi ko tii fidi jokoo daadaa lati sọ wi pe a bẹrẹ sii ṣagbeyẹwo awọn nnkan ti wọn ti n ṣe, ko tii to asiko rara, a fi ti gbogbo nnkan ba ti wa nipo. A fi kawọn araalu ṣe suuru, ati pe emi ko lọrọ kankan lati sọ nipa rẹ, bi ko ṣe pe awọn amugbalẹgbẹ gomina ni wọn le sọrọ."

Nigba to n gbawọn araalu lamọnran, O sọ pe kawọn ọdọ lọọ wa iṣẹ ṣe dibo ki wọn maa bu ẹnu atẹ lu ijọba, ati pe ijọba ati eto oṣelu to wa nita lasiko yi faaye gba a pe ki gbogbo eeyan jade lati wa a da si ijọba to n lọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI