LỌJỌ ỌDUN ILEYA, AWỌN FIJILANTE BANUJẸ NITORI ỌKAN LARA WỌN TO D'OLOOGBE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 12, 2019

LỌJỌ ỌDUN ILEYA, AWỌN FIJILANTE BANUJẸ NITORI ỌKAN LARA WỌN TO D'OLOOGBE

Lasiko tawọn eeyan kaakiri agbaye, paapaa lorilẹ-ede Naijiria ti n ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun Ileya lọjọ Aiku Sande ana, ẹdun ọkan lo jẹ fawọn Fijilante ijọba apapọ, Vigilante Group of Nigeria nipinlẹ Ogun fun bi wọn ṣe padanu ọkan lara wọn, Idowu Aderibigbe laipẹ yi.

Aderibigbe la gbọ pe wọn padanu lasiko tawọn ọlọpaa atawọn Fijilante lọọ kọju ija sawọn ajinigbe ti wọn ji awọn Pasitọ ṣọọṣi Ridiimu, iyẹn The Redeemed Christian Church of God marun un gbe, to si jẹ pe wọn pada ri awọn eeyan naa gba silẹ lọjọ Satide, ọjọ kẹta oṣu yi.

Wọn ni Aderibigbe lo fi ẹmi rẹ lelẹ lagbegbe J3 to wa nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ijẹbu, ipinlẹ Ogun pẹluu ibọn tawọn ajinigbe naa yin fun un lojiji, to si jẹ pe ki wọn to o gbero lati du ẹmi ẹ, o ti ta teru nipa.

Ọjọru Wẹside ọsẹ to kọja yi la gbọ pe wọn sin Aderibigbe siluu  Igbotako to wa nipinlẹ Ondo, to si jẹ pe awọn Fijilante lo ṣagbatẹru isinku naa.

Nigba to n sọrọ, Adari ẹgbẹ VGN naa, Ọgbẹni Nureni Ọlanrewaju Adedoyin sọ pe titi lai lawọn yoo fi maa ṣeranti Oloogbe naa, nitori pe iṣẹ takuntakun lo ṣe ninu ẹgbẹ naa ko too pade iku ojiji.

Bẹẹ lo rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ogun pe ki wọn foju aanu wo ẹgbẹ naa lati fun wọn lawọn nnkan ti wọn nilo lati ṣe iṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ, nitori pe eto aabo ko ṣe e fọwọ yẹpẹrẹ mu lasiko yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI