WỌN FUN IYAALE ILE LỌRUN PA NILE ITURA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, August 2, 2019

WỌN FUN IYAALE ILE LỌRUN PA NILE ITURA

Bo tilẹ jẹ pe iwadii awọn ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ titi dasiko yi, ṣugbọn sibẹ, iyalẹnu lọrọ iku iyaale ile kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Maureen Ewuru ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye, paapaa awọn ara agbegbe D'Line nipinlẹ Port Harcourt.

Ohun ti a gbọ ni pe Maureen ti wọn lo n tọmọ kan ṣoṣo lọwọ ni ọkunrin gbe lọ si ile itura lati jọ jẹgbadun ara wọn, paapaa bi wọn tun ṣe sọ pe obinrin naa n ṣiṣẹ aṣẹwo lati fi toju ara rẹ ati ọmọ kan ṣoṣo to bi silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi iroyin lo n kaakiri ori ayelujara nipa iku Maureen ti a ko si tii le fidi otitọ mulẹ, sibẹ AWIKONKO gbọ pe alẹ ijẹta ni loun ati ọkunrin kan tẹnikẹni ko mọ dasiko yi jọ lọ si ile igbafẹ naa, ti wọn si wọ yara lati gbadun ara wọn.

Wọn ni bi wọn ṣe ba ara wọn sun tan, ti wọn gbadun ara wọn debi to ni apẹẹrẹ ni  wọn sọ pe aawọ bẹ silẹ laarin wọn, to si mu ki ọkunrin naa ki aṣọ mọlẹ, to si fun un lọrun titi to fi ku.
Ṣe ni ọkunrin naa tete ba ẹsẹ rẹ sọrọ nigba to rii pe oun ti pa a danu ki aṣiri ma baa tu sita. A gbọ pe nigba tawọn to ni ile itura naa rii pe ẹnikẹni ko tii jade ninu yara naa laarọ ana, lo mu ki wọn fi tipa wọle, to si jẹ pe oku Maureen ni wọn ba lori bẹẹdi.
Loju ẹsẹ ni wọn ti figbe ta sita, ko too di pe wọn sare lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti kọrọ naa ma ba a yiwọ mọ wọn lọwọ.
Ohun tawọn eeyan n sọ bayii ni pe lara iwadii to yẹ kawọn ọlọpaa ṣe ni pe ki wọn yẹ gbogbo ipe to wọle sori foonu Maureen wo lati mọ ẹni to ṣiṣẹ naa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI