ỌRỌ BURUKU TOUN TẸRIN, DỌKITỌ YỌ EYIN 526 LẸNU ỌMỌDUN MEJE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, August 2, 2019

ỌRỌ BURUKU TOUN TẸRIN, DỌKITỌ YỌ EYIN 526 LẸNU ỌMỌDUN MEJE

Ko sẹni to fẹẹ le kọkọ gbagbọ pe eyin to le ni ẹẹdẹgbẹta lo wa lẹnu eeyan, paapaa bi wọn tun ṣe yọ ẹyin to le ni ẹẹdẹgbẹta lẹnu ọmọdun meje kan lorilẹede India.

Ohun ta a gbọ ni pe ọmọ naa ta a forukọ bo laṣiri la gbọ pe o maa n sunkun pe ẹnu n dun oun ni gbogbo igba, ti ko si tun le jẹun daadaa mọ.

Eyi lo mu kawọn obi rẹ muu lọ ṣayẹwo, ti wọn si ṣakiyesi pe ọpọlọpọ eyin lo wa lẹnu ẹ, eyi ti wọn ni ko bojumu to.

Latigba naa la gbọ pe wọn ti daa duro lati ṣe iṣẹ abẹ fun un, ko le gbadun daadaa, iyẹn ni ile iwosan kan ti wọn pe ni Oral and Maxillofacial Pathology to wa ni Saveetha Dental College and Hospital, India.

Dọkitọ Prathiba Ramani to jẹ olori lọsibitu naa la gbọ pe o ṣiṣẹ abẹ yi, to i sọ pe awọn eyin to je 526 ni iwọn milimita 0.1 si 15 lawọn ba lẹnu rẹ.

A ti ẹ gbọ pe nigba ti ọmọ naa wa lọmọdun mẹta ni wọn ti ṣe awọn akiyesi yi pe ẹnu rẹ yo deede wu soke, ati pe ko ni i gba ki wọn fọwọ kan ẹnu oun nigba naa, eyi ti ko jẹ ki wọn ti ṣe nnkan sii ko too to asiko yi.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI