KASNATY GBỌNA ARA YỌ LORI REDIO TUNTUN ROOTS 97.1FM L’ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, September 4, 2019

KASNATY GBỌNA ARA YỌ LORI REDIO TUNTUN ROOTS 97.1FM L’ABẸOKUTA

Ileeṣẹ Redio kan taye tun n gba tiẹ lasiko yi ni Roots 97.1FM, eyi ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ lopopona Ajebọ, iyẹn lẹyin tẹlifiṣan ipinlẹ Ogun (OGTV) niluu Abẹokuta.

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi eto ni wọn ti la kalẹ, tawọn gbajumọ sọrọsọrọ nipinlẹ Ogun ati agbegbe ẹ si ti n ko ara wọn lọ sibẹ bayii fun arambara eto, ṣugbọn eto ti ọkan lara awọn gbajumọ sọrọsọrọ to filuu Abẹokuta ṣebugbe n gbe oṣuba kare fun bayii, iyẹn Ọgbẹni Kọlawole Adejojo, Kasnaty yatọ gedengbe patapata si tawọn yooku.

Kasnaty tawọn eeyan tun n pe ni Mr Sugar bayii la gbọ pe ara ọtọ lo gba yọ lori eto naa to pe ni Igbadun Express, eyi to n waye ni gbogbo Ọjọru tii ṣe Wẹside laarin agogo mẹwaa owurọ si agogo mejila ọsan (10:00am - 12noon).

Abala mẹrin ọtọọtọ ni eto naa pin si, eyi tawọn eeyan ko ni fẹẹ ma gbọ rara, paapaa julọ nibi tawọn eeyan yoo ti maa fi ẹbu owo ṣe ifajẹ bi wọn ba le dahun awọn ibeere ti ko le rara.

Ọsẹ to kọja ni Kasnaty bẹrẹ eto akọkọ naa, to si jẹ pe gbogbo awọn to gbọ ọ patapata ni wọn n kan saara sii pe "a ṣeto bi ẹni tori ẹ yatọ" ni loootọ, ti ko si ni ẹlẹgbẹ laarin awọn pedepede to wa niluu Abẹokuta.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI