O MA ṢE O: WỌN YINBỌN PA BAALE ILE SINU MỌTO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, September 30, 2019

O MA ṢE O: WỌN YINBỌN PA BAALE ILE SINU MỌTO

Ọpọ awọn to ri oku baale ile kan ti a ko tii mọ orukọ rẹ di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan ni wọn n sunkun ikunlẹ abiyamọ latari bi wọn ṣe fibọn fọ ọpọlọ rẹ jade sita.

 
Bo tilẹ jẹ pe iwadii awọn ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ, sibẹ, iyalẹnu niku ọkunrin tẹnikẹni ko tii mọ naa n jẹ fawọn to ri i. Ilu Lọkọja to wa nipinlẹ Kogi niṣẹlẹ naa ti waye laarọ oni Mọnde gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

 
Inu igbo kan la gbọ pe wọn le ọkunrin naa wọ, ki wọn too pa a mọbẹ. Ohun tawọn kan ti ẹ n sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe mọto ni ọkunrin naa n ta, to si n gbe mọto lọ fun onibara rẹ lati Ekoo ko too pade iku ojiji naa.

 
Diẹ tun re e lara awọn fọto iṣẹlẹ naa.

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI