OWO WA NIDI IṢẸ AJINIGBE, MO TI RI OBITIBITI MILIỌNU KI N TO FIṢẸ NAA SILẸ, Ẹ DARIJI MI - BELLO AUDU, OLORI AWỌN AJINIGBE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, September 13, 2019

OWO WA NIDI IṢẸ AJINIGBE, MO TI RI OBITIBITI MILIỌNU KI N TO FIṢẸ NAA SILẸ, Ẹ DARIJI MI - BELLO AUDU, OLORI AWỌN AJINIGBE

Ọpọ awọn to gbọ bi olori awọn ajinigbe kan lorilẹ-ede Naijiria, paapaa lagbegbe Abuja si Kano ṣe n ka laipẹ yi, ni wọn n rawọ ẹbẹ sawọn ọlọpaa, paapaa ijọba Naijiria wi pe wọn ko gbọdọ jẹ ki ẹlẹṣẹ lọ lai jiya to tọ labẹ ofin.

Laipẹ yi lọwọ ọlọpaa tẹ ọkunrin kan Bello Audu, ẹni ogoji ọdun ti wọn sọ pe ogbologbo olori awọn ajinigbe lorilẹ-ede Naijiria ni, to si ti fi ọpọ ẹmi ati dukia awọn eeyan ṣofo danu laarin asiko to fi huwa naa.

 
A gbọ pe ikọ ọtẹlẹmuyẹ ti ọga agba patapata lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Intelligence Response Team, IRT lo ṣiṣẹ takun-takun lori bi wọn ṣe mu Beloo Audu, to si jẹ pe bi iroyin naa ṣe jade sita ninu ọpọ awọn Naijiria ti n dun pe alaafia yoo de bayii.

Nigba ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo, Bello Audu sọ pe loootọ loun jẹ ajinigbe, toun si ti ji eeyan to le ni aadọta gbe, ko da toun ti gba owo ti ko din ni ọgọrun miliọnu naira lọwọ awọn toun n ji gbe naa, ati pe oun tun ti pa lara awọn toun ti gbe, ti wọn ko ri owo fi silẹ lati gba ara wọn silẹ.

 
O ni boun ba ti da mọto duro lopopona marosẹ eyikeyi, oun yoo ri i daju pe oun gba owo lọwọ gbogbo wọn ki wọn to le gba ara wọn silẹ. Diẹ re lara nnkan to sọ.


"Latigba ti mo ti pada si abule ni mo ti n ṣe jẹjẹ, ti mi o huwa buruku mọ. mo wa ninu iṣẹ adigunjale ati ijinigbe tẹlẹri. Mo ti ji eeyan to to aadọta (50) gbe. Mo si ti gba miliọnu mẹta naira lẹẹmẹta ọtọọtọ.

 

"Mo ti gba miliọnu mẹwaa naira, miliọnu mẹtadinlogun naira, miliọnu mọkandinlogun naira ati bẹẹbẹẹlọ loriṣiriṣi ọna. aarin ilu Abuja si Kaduna ni mo ti n ṣọṣẹ mi. Mo tun maa n lo awọn ọmọ kekeeke atawọn eeyan labule mi ni Maidaro. Awọn ọmọ nidi iṣẹ yi wa ni Katsina ati Zamfara. Oriṣi ọna mẹsan ni wọn tẹdo sii.


"Ibọn AK47 ni mo maa n lo, ẹgbẹrun lọna aadọta ni mo si maa n ra ibọn mi lọwọ Alaaji kan ti wọn n pe ni Yaro Alaaji, agbegbe Kajori lo wa. Mọto ẹlẹru (Container) nla kan ni mo ma fi n ko nnkan ija oloro wọle. Ẹgbẹrun kan naira ni ọtan ibọn kan ṣoṣo.

 

"Mo ti pa eeyan to to mẹwaa. Ọkan ti ẹ wa lara wọn ti mi o fẹ pa, ṣugbọn tori pe awọn mọlẹbi ẹ ṣepe fun mi lori foonu lo jẹ ki n pa danu. Awọn min in ti mo tun pa ni pe awọn mọlẹbi wọn ko ri owo san lati gba wọn silẹ. Mo ni maalu ti ko din ni igba, ti mo n sin .


"Tẹlẹ ni mo n ṣe awọn nnkan wọnyii, ṣugbọn mi o ṣe wọn mọ bayii, tori pe mo ti fi silẹ. Ti m ba pe ẹgbọn mi, Alaaji Abu, o maa ko gbogbo awọn irinṣẹ ti mo n lo tẹlẹ naa wa."

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI