SATIDE ẸRẸBẸ: LAARIN DAPỌ ABIỌDUN ATI ADEKUNLE AKINLADE, IPINLẸ OGUN YOO MI TITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 13, 2019

SATIDE ẸRẸBẸ: LAARIN DAPỌ ABIỌDUN ATI ADEKUNLE AKINLADE, IPINLẸ OGUN YOO MI TITI

Gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun patapata ni wọn ti n gbaradi bayii fun ọjọ Abamẹta Satide ọla, nigba ti ẹlẹkun yoo sunkun, ti alayọ yoo si yọ.
 
Abajade esi idajọ ile ẹjọ Tribuna to fẹẹ waye lawọn eeyan n duro de bayii. Nigba tawọn ọmọ lẹyin Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun n sọ pe ko si nnkan o fẹẹ ṣẹlẹ, tori pe ẹjọ ti Ọnọrebu Adekunle Akinlade, Triple A pe ko lẹsẹ nilẹ rara.

Bẹẹ lawọn ọmọlẹyin Ọnọrebu Akinlade naa n gbaradi bayii, ko da a, ti a gbọ pe gbogbo eto ti to patapata lati dana ariya, bi ile ẹjọ ba le kede ọga wọn gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina to waye lọjọ kẹsan an oṣu kẹta ọdun yi.

Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ daadaa, wọn a mọ pe lati gba ti ajọ INEC to n dari eto idibo lorilẹede Naijiria ti kede Ọmọba Dapọ Abiọdun ni Ọnọrebu Akinlade toun gbe apoti labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM ti pe ẹjọ ti nọmba ẹ jẹ EPT/OG/GOV/01/19 nile ẹjọ Tribuna pe oun ko gba esi ibo naa wọle rara, tori pe madaru wa nibẹ.

Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni wọn sọ pe ibo 222,153 lo gbe e wọle, nigba ti Ọnọrebu Akinlade, Triple A ni ibo 241,670, ti Ọmọba Goyega Nasir isiaka to ṣe ipo kẹta si ni ibo 110,422 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC.

Lọjọ kọkandinlogun ni Onidajọ Yusuf Halilu to n dari ẹjọ naa, lẹyin awọn abajade ti igbẹjọ naa sọ pe kawọn ti wọn n ja si ipo gomina lọ maa gbaradi fun ọjọ kẹrinla oṣu yi, tii ṣe ọla fun idajọ, nitori pe ọjọ naa i onikaluku wọn yoo mọ ipo to wa.

Nnkan to daju bayii ni pe, bi idajọ naa ko ba tẹ ẹgbẹ oṣelu APM lọrun, ile ẹjọ kotẹmilọrun lo n gba lọ, bẹẹ gẹlẹ naa lo ri fun Gomina Dapọ Abiọdun bi ile ẹjọ ba da Ọnọrebu Akinlade lare.

Bẹ o ba gbagbe, ko fẹẹ si iyatọ laarin ẹjọ to n lọ lọwọ yi si ẹjo ti Sẹnẹtọ Ademọla Adeleke to jẹ oludije sipo Gomina nipinlẹ Ọṣun lọdun to kọja pe akẹgbẹ ẹ to jawe olubori, Alaaji Gboyega gboyega Oyetọla, nibi to ti sọ pe esi ibo naa ko tẹ oun lọrun.

Ẹ gbọ, bawo ni yoo ṣe ri lara yin bi ile ẹjọ ba da Gomina Abiọdun lare, ati pe bawo ni yoo ṣe ri lara yin bi ile ẹjọ ba da Ọnọrebu Akinlade lare?

Ẹ jẹ ka gbọ ero ọkan yin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI