TRIBUNAL: GỌNGỌ YOO SỌ KAAKIRI NAIJIRIA LONII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 11, 2019

TRIBUNAL: GỌNGỌ YOO SỌ KAAKIRI NAIJIRIA LONII

Gbogbo agbaye ni wọn ti gbaradi lasiko ti a ṣakojọpọ iroyin tan fun ti idajọ to fẹẹ waye fun idibo Aarẹ orilẹede Naijiria to waye loṣu keji ọdun yi, eyi to gbe Aarẹ Muhammadu Buhari wọle lẹẹkeji.

Ilu Abuja ni idajọ naa yoo ti waye, tawọn oluwoye atawọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn Ololufẹ Aarẹ Muhammadu Buahri ati alatako ẹ, toun jade dupo labẹ asia ẹgẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ti woye ibi ti ẹjọ naa yoo yọri sii.

Awọn kan ti ẹ n ti n beere lọwọ ara wọn wi pe 'bawo ni yooo ṣe ri lara wọn bi wọn ba kede Atiku Abubakar gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori', ti idahun si n lọ loriṣiriṣi, iyẹn lori ikanni ayelujara.

Onidajọ Mohammed Garba to jẹ Aarẹ ile ẹjọ Tribunal la gbọ pe awọn ọmọlẹyin Atiku Abubakar ti n sọ pe ko kede ọga wọn gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori nibi idibo, paapaa bawọn ẹri aridaju ṣe jẹyọ, tawọn si foju rii, tabi ki wọn tun ibo naa di.

Ẹ gbọ, bawo ni yoo ṣe ri lara yin bi wọn ba kede Atiku Abubakar gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori, tabi ti wọn ba ni ki Aarẹ Buhari maa ba iṣẹ rẹ lọ?

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI