XENOPHOBIA: IRINWO ỌMỌ NAIJIRIA NI WỌN TI GBARADI LATI FI ORILẸ-EDE SOUTH AFRIKA SILẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 8, 2019

XENOPHOBIA: IRINWO ỌMỌ NAIJIRIA NI WỌN TI GBARADI LATI FI ORILẸ-EDE SOUTH AFRIKA SILẸ

Awọn ọmọ Naijiria ti ko din ni irinwo la gbọ pe wọn ti forukọ silẹ lati fi orilẹ-ede South Afrika silẹ latari bawọn ọmọ orilẹ-ede naa ṣe doju ija kọ wọn, ti wọn si n pa wọn nipakupa bi adiẹ irana.

Ajọ kan ti wọn pe ni Nigerian Mission lorilẹ-ede South Afrika ni wọn fidi ọrọ naa mulẹ laipẹ yi pe awọn ti ṣetan lati ko awọn eeyan naa pada si orilẹ-ede wọn, lati le gba wọn lọwọ iku ojiji to n doju kọ wọn.

A gbọ pe ọkọ baalu ọfẹ ile iṣẹ Air Peace lo gbe eto naa kalẹ lati ko awọn eeyan naa kuro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI