AKEREDOLU LE AMUGBALẸGBẸ RẸ DANU NITORI AṢEMAṢE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 7, 2019

AKEREDOLU LE AMUGBALẸGBẸ RẸ DANU NITORI AṢEMAṢE

Gomina ipinle Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti le ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ oṣelu, Ọgbẹni Augustine Pelemọ danu latari ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an.

Lonii ni wọn jawe lọ gbele ẹ fun ọkunrin naa, ninu atẹjade ti Kọmiṣana lori ọrọ iroyin ati bo ṣe n lọ, Ọgbẹni Donald Ojogo fi sita lo ti sọ pe ipinlẹ naa nilo awọn to kaju oṣuwọn daadaa.

O nijọna gomina Akeredolu ko faaye silẹ fun magomago tabi ijẹnilẹsẹ, idi ni yii tawọn fi gbọ yọ eepo kuro ninu alikama to ṣee ṣe ko ba ijọba wọn jẹ. 

Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe ijọba ti paṣẹ pe ki Ọgbẹni Pelemọ lọọ ko gbogbo awọn ẹru to jẹ ti ijọba silẹ, ko si lọọ fi to igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI