ẸGBẸ OṢELU APC ATI BUHARI WỌ GAU, NITORI JONATHAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, October 7, 2019

ẸGBẸ OṢELU APC ATI BUHARI WỌ GAU, NITORI JONATHAN

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP)  lọjọ Sande ana ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ tijọba Aarẹ Muhammadu Buahri ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) sọ nipa iṣejọba Oloye Goodluck Ebele Jonathan wi pe awọn ni wọn ko orilẹ-ede Naijiria wọnu oko gbese latari iwa ajẹbu ti wọn fi ṣayọ lasiko wọn.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Kọla Ọlọgbọndiyan fi sita lo ti jẹ ko ye awọn ọmọ Naijiria wi pe ọrọ ti ẹgbẹ oṣelu APC ati Aarẹ Buhari n sọ nipa Aarẹ ana, Goodluck Jonathan ko lẹsẹ nilẹ rara nitori pe ọna lati ṣi ọkan awọn eeyan kuro nibi iwa ajẹbanu to n lọ lasiko yi ni wọn n wa.

O ni ijọba Buhari ko kaju oṣuwọn lati gbe Naijiria gun oke agba lo mu ki wọn maa wa ọrọ atamọ lati fi gbe aiṣedeede wọn nidii, kawọn ọmọ Naijiria ma ba a ri awọn aṣiṣe wọn, ati pe ijọba wọn kun fun iwa ajẹbanu pupọ ninu itan.

Ẹ ka a siwaju sii ỌRỌ ỌLỌGBỌDIYAN

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI